Alagá PDP ti gbé Lai Mohammed lọ ilé ẹjọ́

Uche Secondus

Oríṣun àwòrán, Twitter/@uchesecondus

Alaga ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Uche Secondus, ti mú ẹjọ́ minísítà fun ìròyìn atí àṣà Nàìjíríà, Lai Mohammed , lọ silé ẹjọ́ lorí ẹ̀sún ìbánílórúkọ́jẹ́, o sì ń fẹ́ kí mínísítà náà san bílíọ́nù kan àbọ̀ fún òun.

Secondus gbé ìgbesè yìí ni lẹyín ìgbà tí Mohammed fi órúkọ́ rẹ̀ sinú órúkọ́ àwọn ti ìjọba f'ẹ̀sun kíkówó jẹ́ kàn.

Ẹgbẹ́ òṣẹ̀lú PDP ti kọ́kọ́ fún minisita náà ni ọjọ́ mejì ko fi dá ọ̀rọ̀ náà padà.

Ọ̀gbẹ́ní Secondus ń fẹ́ kí Lai Mohammed tọrọ àforijì lẹyín ìgbà tó bá dá ọ̀rọ̀ náà padà gẹ́gẹ́ bi ìwe ìpẹ̀jọ náà fi hàn.