Wo fídíò bí Fẹ́mi Ọ̀tẹdọlá ṣe wọ ọkọ-akér ni London

Fẹ́mi Ọ̀tẹdọlá ninú ọkọ-akéro ni London

Oríṣun àwòrán, Instagram/@Femiotedola

Ko si ńǹkan túntún nipa wiwọ okọ̀ akéro ti a mọ̀ si bọ́si, sùgbọ̀n àwọn eeyán ti ń pin fídíò bi Fẹ́mi Ọ̀tẹdọlá ṣe wọ ọkọ̀ akérò nígboro London lórí ẹ̀rọ-ayélujára.

Alága ilé iṣẹ́ Forte Oil to jẹ ọ̀kan lara àwọn ti wọn ni owó jù ni Nàìjíríà sọ wipe òun wọ ọkọ̀ náà ni lati lọ ri olukọ òun tẹlẹ̀ri, Wandsworth.

Sùgbọn àwọn ọmọ Nàìjíríà ti wo fídíò ọ̀hun nigba ẹ́gbẹ̀run l'ọ́ná ogọ́talénígba ( 260,000) lori òpó Instagram láàárin ọjọ́ mẹ́ta ti Ọ̀tẹdọlá fi fídíò ọ̀hun s'ọwọ si ori òpó náà.

Wọn si s'ọ̀rọ̀ nipa fídíò náà nigba ẹgbẹ̀run kan àti àádọ́rùúlénírínwó (1,490).

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ síí: