Ọwọ ọlọ́pàá ti tẹ́ afurasí 7 lórí ìdigúnjalẹ́ Ọ́ffà

Offa attack

Oríṣun àwòrán, Ayobami Agboola

Àkọlé àwòrán,

Guaranty Trust Bank Offa, Kwara state

Iléeṣé ọlọ́pàá ti ìpinlẹ Kwara ni iyé àwọn ti wọn ku nibi ìdigúnjalé àwọn ilé ìfowó pamọ si ni Ọ́ffà ti di mẹ́tàdínlogun.

Agbennusọ fún ọlọ́pàá ni ìpinlẹ̀ náà, Okasannmi Ajayi, sọ fún BBC wipe mẹ́san ninú àwọn eeyáy mẹ́san ninu mẹ́tàdínlogun to ku ọ̀hun, ọlọ́pàá ni wọn, nigba ti mẹ́jọ́ jẹ alágbádá.

Botilẹ̀ jẹ́ wipe àwọn iwe ìròyìn kan sọ pe ọgbọ́n èèyán lo ku ninú ìkọlu náà, ọga ọlọ́pàá ọhun sọ wipe àwọn ti wọn ku wọn ku ju ọgbọ lọ

O sọ wipe àwọn ti wọn farapa nibi ìkọlù náà wa ni àwọn ilé ìwosan ìlú Ọ̀ffà ati ti ilè ẹ̀kọ gígá Ìlọ́rín.

O si sọ wipe lẹyín afurasi mẹ́jẹ́ ti wọn mu, ọwọ olọ́pàá ti tẹ ọkọ̀ méjé àti àwọn ẹ̀rọ́ ìbanisọ̀rọ̀ ti àwọn ọlọ́ṣà náà lo nibi ìkọlù ọ̀hun.

O sọ wipe gómináà ìpinlẹ̀ náà Abdulfatah Ahmed, ti kedé ẹ̀bún mílíọ̀nù marú naira fún gbogbo ẹ̀ni to ba le ṣ'àlàyé bi wọn yóò ṣe mu àwọn adigujalè náà.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kwara State Government

Kin ní ńǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Ọ́ffà

Ìlú Ọ̀ffà ní ìpínlẹ̀ Kwara wárìrì lọ́jọ́bọ, tí kowéè ké láì ha, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè kan tó wáyé nílé ìfowópamọ́ márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú náà.

Àwọn eeṣin kò kọ ikú adigunjalè náà, tí wọ́n tó ọgbọ̀n níye ló ṣe ọṣẹ́ láwọn báńkì náà fún wákàtí méjì àti ààbọ̀ gbáko, èyí tó sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di opó àti ọmọ òrukàn.

Kí aráyé baà leè mọ̀ pé eré kọ́ làwọn wá ṣe, àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Owódé làwọn alọkólóhunkígbe yìí ti kọ́kọ́ kí wọn kú ilé níbẹ̀, tí wọ́n sì rán àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́, àwọn èèyàn tó ní ẹjọ́ ní tésàn náà àtàwọn èèyàn míì tó wà níbẹ̀ sọ́run ọ̀sángangan.