MMM ti kógbá wọlé

Sergei Mavrodi

Oríṣun àwòrán, https://nigeria-mmm.net/news/

Níbáyìí, àwọn ti wọ́n lọwọ ninú sogúndogójì MMM wọ́n yóò mọ iyé owó ti wọ́n pàdanù nigbà tí àwọn alákósó rẹ̀ ti fi òpin síi.

Àwọn alákósó opó MMM lórí ẹ̀rọ ayélujara sọ wipe ńǹkan tí ó faà tí àwọn fi tií ni pe àwọn ko le maá bá etò sogúndogójì náà lọ laì sí ọ̀ga wọ́n tó dí olóògbẹ, Sergei Mavrodi.

Àtẹ̀jadé náà sí sọ wipe gbogbo àwọn ti wọn kopa ninú MMM ti mọ nipá ewu to wà nibẹ ki wọ́n ó tó ti ẹsẹ̀ bọọ́.

Wọ́n ni gbogbo ìgbìyanju atí tẹ̀siwaju pẹ̀lú sogúndogójì ọ́hun kò ní ṣeéṣé.