Sòwòrẹ́: Èmi kò leè bá jẹgúdújẹrá APC àti PDP se pọ̀

Sòwòrẹ́: Èmi kò leè bá jẹgúdújẹrá APC àti PDP se pọ̀

Olùdásílẹ̀ iléesẹ̀ ìròyìn Sahara Reporters, tó tún fẹ́ du ipò ààrẹ ní Nàíjíríà kéde pé, àwọn jẹgúdújẹrá ló wà nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC àti PDP, nítorínà àwọn ti ń fọwọ́sowọ́pọ̀ láti dá ẹgbẹ́ alájùmọ̀se kan sílẹ̀,

Sòwòrẹ́ tún ní, òun kìí se ọmọdé láti du ipò ààrẹ nítorí òun ní ìrírí púpọ̀ láti se àkóso yátọ̀ sí ìrírí olè jíjà, ìbàlújẹ́ àti ìfọmọsowó táwọn olósèlú kan ní.

Ó ní àwọn ọ̀dọ́ ló ń darí ìlú láwọn orílẹ̀èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: