Èèyàn mẹ́fà kú nílé isẹ́ ìwakùsà ní Ghana

àwọn ibi ìwakùsà lóri'lẹ̀èdè Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìjàmbá ti sekú pa àwọn ènìyàn ni àwọn ibi ìwakùsà lóri'lẹ̀èdè Ghana.

Oun tó tó èèyàn mẹ́fà ni a gbọ́ pe wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí wọn ninu ìjàmba kan to waye nílé isẹ́ ìwakùsà Newmot lorilẹede Ghana.

Newmot ti ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀ún ti sẹlẹ̀ jẹ́ iléese to wa lati ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Àjà ọ̀kan lara awọn àjaàlẹ̀ ti wọn ti n wa àlùmọ́ọ́nì góóòlù ni wọn ni o já lé awọn eniyan ọun lórí ti ọ̀pọ̀ ninu wọn náà sì farapa.

Awọn alẹ́nulọ́rọ̀ ti sọ pe wọ́n ti dásẹ́ dúró fúngbà díẹ̀ na lati sèwádìí ọ̀rọ̀ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

ọ̀pọ̀ ilé isẹ́ ìwakùsà ti ìjàmbá ti n sẹlẹ̀ ni ọ́ jẹ́ èyí tíkò b'ófin mu

Newmont tó jẹ́ ọ́kan lara àwọn ilé isẹ́ tó n wa oun àlùmọ́ọ́nì góóòlù tó tóbi jù lágbááyé ni ó ní ilé isẹ́ ìwakùsà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀èdè Ghana .