Ìsẹ̀lẹ̀ Èkó: Ọmọge fẹsẹ̀ fẹ nígbàtí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ rì sómi nílé ìtura

Àwọn èèyàn tó ń lúwẹ̀ẹ́ nínú adágún odò ní ilé ìtura Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ìgbà láwọn èèyàn máa ń lọ lúwẹ̀ẹ́ nínú adágún odò ní ilé ìtura

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ọwọ́ epo ni ọmọ aráyé máa ń báni lá, wọn kìí bá ni lá ọwọ́ ẹ̀jẹ̀, ìdí rèé tí ọmọge kan ṣe fẹsẹ̀ fẹ́ẹ nílé ìtura kan ní àdúgbò Ishashi ní ìlú Èkó nígbàtí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tí wọ́n jọ wá rì sínú omi tí wọn fi ń lúwẹ̀ẹ́ nílé ìtura náà.

Ní kété tí wọn sì rí òkú ọkùnrin náà ni wọ́n késí àwọn ọlọ́pàá, tí wọn yọ òkú náà, tí wọ́n sì gbée sílé ìwòsàn ní ọjọ́ kejọ̀, osù kẹrin tí ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSòwòrẹ́: Èmi kò leè bá jẹgúdújẹrá APC àti PDP se pọ̀

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó, tó fìdí ìsẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní, wọn kò tíì mọ ẹnití ọkùnrin naa jẹ́ àti ibití ó ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rí ojú ọgbẹ́ ní ara òkú náà.

"Ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni obìnrin tí wọn dìjọ wá ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, tí wọn kò sì rí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ alágbèéká ní ara òkú náà láti mọ ẹni tó jẹ́. A sì ti gbé òkú náà sí ibùdó ìgbókùúsí tó wà ní ilé ìwòsàn ìjọba ní ìlú Badagry."