Sàràkí: Orúkọ àwọn tó kówó ìlú mì tíjọba se kò dára tó

Sẹ́nétọ̀ Bùkọ́lá Sàràkí Image copyright Nigeria Senate
Àkọlé àwòrán Dúkùú láàárín ẹ̀ka ìṣèjọba lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ti di ìsẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́

Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Bùkọ́lá Sàràkí ti sọ pé, kò sí bí àjọṣepọ̀ tó gún ṣe lè wà láàárín ẹ̀ka ìṣàkóso ìjọba àti aṣòfin nítorí ìwà àìfinipeni, àìfèèyànpèèyàn.

Sẹ́nétọ̀ Bùkọ́lá Sàràkí ní, nìwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ka ìṣàkóso bá ń nàka 'olè ni ọ́' sí ẹ̀ka tó kù, àláfíà kò lè ṣí.

Sàràkí sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi àpérò kan tó wáyé ní ìlú Jos, lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Bílíọ̀nù kan dọ́là tí ẹ̀ka aláṣẹ kéde láti ra ohun ìjà ogun ló ṣeéṣe kó tún fa wàhálà míì

Ọ́ ṣàlàyé pé, bí ẹ̀ka ìṣèjọba bá ń nàka àléébù sí ẹ̀ka míràn, kò sí bí nǹkan yóò ṣe dán mọ́rán.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ààrẹ iléègbìmọ̀ aṣòfin àgbà lórílẹ̀èdè Nàìjíríà wá bu ẹnu àtẹ́ lu ìwé orúkọ àwọn tó kó owó ìlú jẹ, èyí tí ìjọba Buhari ń gbé kiri báyìí gẹ́gẹ́ bíi èyí tó kù díẹ̀ káàtó.

Bákannáà ni, Sàràkí tún yànànà ìhà tí àwọn aṣòfin àgbà kọ sí ìkéde bílíọ̀nù kan dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ẹ̀ka aláṣẹ ṣe láìpé yìí, láti fi pèèlò ohun ìjà ogun tuntun fún àwọn ọmọ ogun tó ń kojú u ìpèníjà ààbò káàkiri tìbútòró orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán 'Dídẹ́yẹsí àwọn ẹ̀ka ìṣèjọba tókù kò leè so èso rere fún ìdàgbàsókè orílẹ̀èdè Nàìjíríà'

Ọ́ ní dídẹ́yẹsí àwọn ẹ̀ka ìṣèjọba tókù kò leè so èso rere fún ìdàgbàsókè orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ó ní ìwà àìfinipeni, àìfèèyànpèèyàn tí ẹ̀ka aláṣẹ ń hù ló ń fa dúkùú lọ́pọ̀ ìgbà, láàárín ẹ̀ka aláṣẹ àti àwọn aṣòfin lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.