CAN: Ẹgbẹ́ àwọn pásítọ̀ náà ṣàjèjì sí ẹgbẹ́ wa

Àwọn pásítọ̀ kan ń bọ Buhari lọ́wọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò wọn Image copyright @AsoRock
Àkọlé àwòrán Ariwo bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn asáájú ẹ̀sín krìstẹ́nì nítorí àbẹ̀wò àwọn pásítọ̀ kan sí Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí

Ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Krístì lórílẹ̀èdè CAN ti sọ èrèdì rẹ̀, tí ẹgbẹ́ náà fi kẹ̀yìn sí àwọn pásítọ̀ kan, láti ẹkùn àríwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà, tí wọ́n bẹ Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí wò láìpé yìí.

Nínú àtẹ̀jáde tí CAN fi ṣọwọ́ sí BBC Yoruba, ó ní, ìdí àkọ́kọ́ ni pé, ẹgbẹ́ àwọn pásítọ̀ náà ṣàjèjì sí ẹgbẹ́ CAN, àti pé ẹgbẹ́ náà kúkú ti jẹ́wọ́ ara rẹ̀ pé àwọn kìí ṣe ara CAN.

Ìdí kejì ni pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ẹgbẹ́ yìí lọ sí ọ̀dọ̀ Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí, láì pè fún ìtúsílẹ̀ Leah Sharibu àtàwọn akẹ́kọ Chibok to kù láhámọ́ àwọn Boko haram.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSòwòrẹ́: Èmi kò leè bá jẹgúdújẹrá APC àti PDP se pọ̀

Bákannáà ni wọ́n ní kàyééfì ńlá ló jẹ́ pé àwọn pásítọ̀ náà kò sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù àti ìpànìyàn tó ń wáyé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àbẹ̀wò náà ń mú ọ̀pọ̀ awuyewuye lọ́wọ́

CAN kò ṣàì kọminu lórí ohun tí àwọn pásítọ̀ náà sọ pé àwọn alátakò ń lo àwọn pásítọ̀ kan láti tako Bùhárí.

Lọ́sẹ̀ tó kọjá làwọn pásítọ̀ kan lábẹ́ àṣíá ẹgbẹ́ àwọn pásítọ̀ lẹ́kùn Arewa tó ń fẹ́ àláfíà, APPIN, bẹ Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí wò ní Abúja.