Irú èèyàn wo ni Akínwùmí Ìṣọ̀lá jẹ́?

Oloogbe Akinwunmi Ishọla Image copyright @MobilePunch
Àkọlé àwòrán Oloogbe Ishọla lo kọ iwe Ẹfunsetan Aniwura

Kìí ṣe ìròyìn mọ́ wí pé ògbóǹtagí òǹkọ̀tàn àn nì, Akínwùmí Ìṣọ̀lá ti dágbére fáyé.

Àmọ́ṣá, lọ́jọ́ ìṣẹ́gun ni ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ kí wọ́n tó gbé e wọ káà ilẹ̀ lọ lọ́jọ́ ẹtì.

Gẹ́gẹ́ ́bíi ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ àti ìgbé ayé olóògbé Ìṣọ̀lá, ìpapòdà èèkàn ìmọ̀ èdè Yorùbá náà ti ṣílẹ̀kùn ààyè ńlá sílẹ̀ tí yóò ṣòro láti dí.

Wọ́n wòye pé, gẹ́gẹ́ bíi òǹkọ̀wé, agbáṣàga, olùkọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ẹyẹ tí yóò ṣe bí àdán an Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Ìṣọ̀lá ṣọ̀wọ́n.

Díẹ̀ nínú ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àṣà àti èdè Yorùbá sọ nípa ọ̀jọ̀gbọ́n Ìṣọ̀lá nìyí:

Ọ̀jọ̀gbọ́n Dúró Adélékè. Fásitì ìlú Ìbàdàn, UI

Òǹkọ̀wé tí kò fi àṣà àti ìṣe Yorùbá ṣeré ni. O gbé èdè Yorùbá lárugẹ títí dé òkè òkun.

Ní kíkọ, ó kọọ́; ní ṣíṣe, ó ṣe è. Gbogbo ẹ̀ka èdè ló ti pegedé bíi ìwé kíkọ àti eré ìtàgé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTunde Kelani k'ẹdun iku Akinwunmi Ishola

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwálé. Fásitì ìlú Ìlọrin, UNILORIN

Nǹkan tí èmi mọ̀ ni tó ṣe kókó jù nípa Olóyè Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Ìṣọ̀lá ni p, ó ṣiṣẹ́ takuntakun láti gbé àṣà Yorùbá lárugẹ. O sì ṣiṣẹ́ yìí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tó kọ sílẹ̀ tí kò lè parun.

Ẹni tó mọ ọ̀rọ̀ ń kójọ ni. Tí wọ́n bá kọ ìwé tàbí eré ìtàgé wọ́n mọ ọ̀rọ̀ ń kó jọ tí yóò níkìmí.

'Honest man' (olóòótọ́ ènìyàn) ni ìnágijẹ bàbá nígbà tí wọ́n wà láyé nítorí èèyàn iyì ni wọ́n.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Táíwò Olúǹládé. Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó, LASU

Ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀ tó yanrantí ni wọ́n, ní ìgbà ayé e wọn. Kò sí akẹ́kọ́ tí kìí sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere.

Wọ́n kọ́ mi ní fásitì, mo mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ni tó dáńtọ́ tó sì ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn.