Ìbúgbámù ṣe'kú pa èèyàn kan ní Ilẹ̀ ifẹ̀

Àwókù ilé ìtoògùn náà Image copyright Baba oloye
Àkọlé àwòrán Ìbúgbámù náà wáyé nílú Ilé ifẹ̀ lóru ọjọ́ àbámẹ́ta

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ pé àwọn kò tíì leè sọ bóyá àdó olóró ló bú nílééṣẹ́ ìtoògùn kan ní ìlú Ilé ifẹ̀.

Ìbúgbámù kan wáyé ni iléeṣẹ́ apoògùn kan níÌlú Ilé ifẹ̀ lóru ọjọ́ àbámẹ́ta sí àìkú.

Iléeṣẹ́ apoògùn náà tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Ebenco ni ìròyìn sọ pé àwọn èèyàn tí gbọ́ ìróo ìbúgbàmù eléyìí tó da ilé náà wó lu lẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌbúgbámù ṣekú pa èèyàn kan ní Ilé ifẹ̀

Nínú ìfòròwánilénuwò tó ṣe pẹ̀lu BBC Yorùbá, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọláfimíhàn Adéoyè ní ìwaàdí ni yóò sọ ní pàtó, ohun gan tó ṣokùnfà ìbúgbámù náà."Èèyàn kan tó ṣèṣe nínú ibu ìbúgbámù ọ̀hun padà kú. Ṣùgbọ́n ìwaàdí ni yóò fìdí òkodoro ọ̀rọ̀ múlẹ̀"

Image copyright Baba oloye
Àkọlé àwòrán Ọlọ́pàá ní ìwaàdí ni yóò sọ bóyá àdó olóró ni

Ọ̀gá ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun sọ pé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò wáyé rí, àwọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun àtúnṣẹ̀ rẹ̀.

Nígbà tí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, Ọláfimíhàn Adéoyè bẹ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù náà ti ṣẹ̀lẹ̀ wò lọ́jọ́ ajé, ó ní àwọn agbófìnró yóò máa ṣètò àbò tó gbópọn fún àwọn aráàlú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: