Buhari yóò ṣèpàdé pẹ́lú Theresa May lórí ọ̀rọ̀ Nigeria

Ààrẹ Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Buhari yóò ṣèpàdé pẹ́lú Theresa May lórí ọ̀rọ̀ Nigeria

Ààrẹ Muhammadu Buhari tẹkọ̀ òfurufú létí lọ sí bẹ ìlu Ọba fún ìbẹ̀wò isẹ́ sáájú ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀èdè Commonwealth èyí tí yóò wáyé ní ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹrin ọdún yìí.

Lasiko àbẹ̀wò náà, yóò se ìpàdé pẹ̀lú olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May àti àwọn èèkàn mìíràn lórí àwọn ìpènijà tí orílẹ̀èdè Nigeria ńdojú kọ àti ọ̀nà àbáyọ.

Bákan náà, ààrẹ Buhari yóò pàdé pẹ̀lú Bísọ̀ọ̀bù àgbà ti Canterbury, ẹni ọ̀wọ̀ jùlọ Hon. Justin Welby ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Malam Garba Shehu, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ àgbà fún ààrẹ lórí ìròyìn sọ wípé ààrẹ Buhari àti olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May yóò tún jíròrò lórí àjọsepọ̀ láàrin orílẹ̀èdè Nigeria àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ awuyewuye ló tọ àbẹ̀wò rẹ̀ àkọ́kọ́ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Láfikún, ààrẹ yóò sèpàdé pẹ̀lú ọ̀gá pátátá ilé isẹ́ Royal Dutch Plc, Ben van Beuden lórí àwọn ètò tí ilé isẹ́ Shell àtàwọn alájọsepọ̀ wọn ní láti dókoòwò iye owó bílíọ̀nù dọ́là mẹ́ẹ̀dógún sínú owò epo orílẹ̀èdè Nigeria.

Ní ọdún tó kọjá, ẹ̀ẹ̀mẹ́jì ni ààrẹ Buhari ti lọ si ìlú London lórí ìlera rẹ̀ kó tó padà nínú osù kẹjọ.

Ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀èdè Commonwealth yóò wáyé láàrin ọjọ́ kejìdínlógún ọdún yìí sí ogúnjọ́ osù kẹrin.

Ẹ̀wẹ̀, kò tíì dájú iye ọjọ́ tí yòó lò.