Àgbáríjọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ AAUN fẹ̀hónú hàn nípìnlẹ̀ Òndó

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ̀hónú hàn nípìnlẹ̀ Òndó Image copyright AAUA News Forum
Àkọlé àwòrán Ọlọ́pàá yìnbọn fún akẹ́kọ̀ọ́ AAUA

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Adekunle Ajasin, Akungba-Akoko tú síta kẹ̀tí-kẹ̀tí lónì''i láti fẹ̀hónú hàn lórí i àfikún owó iléèwé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Òndò paláṣẹ.

BBC Yorùbá ri gbọ́ wípé ìfẹ̀hònúhan náà wáyé ní ìlú Àkùngbá-Àkókó àti ìlú Àkúrẹ́ tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Òndó.

Ààrẹ fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ Òndó ní fásitì nàá, Popoọla Morayọ Samson sọ fún BBC pe ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó ṣèlérí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá láti fi tùwọ́n l'ójú. Ṣùgbọ́n, ó ní àwọn kò fẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nàá, ẹ̀dínwó owó ilé-ìwé l'àwọ́n fẹ́.

Owó ilé-ìwé tó kéré jù tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá n san tẹ́lẹ́ ni ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún lé ọgọ́rùn ún Náírà, ṣùgbọ́n tí ìjọba ti sọ di ààdọ́jọ ẹgbẹ̀rún Náírà.

Image copyright AAUN News Forum
Àkọlé àwòrán Akitiyan BBC láti bá iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Òndó jásí pàbó

Ó fi kun pé fásitì nàá ni owó rẹ̀ kéré jùlọ tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà.

Lásìkò ìfẹ̀hónúhàn nàá, a gbọ́ wípé àwọn ọlọ́pàá gbìyànjú láti fi afẹ́fẹ́ tajú-tajú tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá ka. Bákanna ni Popoọla Morayọ sọ wípé wọ́n yin ìbọn mọ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá l'ẹ́sẹ̀.

Akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ló ní wọ́n ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Image copyright AAUN News Forum
Àkọlé àwòrán Owó ilé-ìwé tó kéré jù tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá n san tẹ́lẹ́ ni ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún lé ọgọ́rùn ún Náírà

Ẹ̀wẹ̀, ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fásítì nàá, Awoṣika Ayọdapọ sọ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàdé l'àwọn ti ṣe pẹ̀lú ìjọba, ṣùgbọ́n tí wọ̀n kò gbìpẹ̀.

Akitiyan BBC láti bá iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Òndó jásí pàbó.

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: