Sáà kejì Ààrẹ Bùhárí: Àwọn ọmọ Nàíjíríà f'èrò wọn hàn

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption"Ẹ jẹ́ kí Buhari lọ jókòó"

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti fi ero wọn han lori bi Aarẹ Muhammadu Buhari se fi ipinnu rẹ han lati dije fun ipo aarẹ lẹlẹẹkeji ni idibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun 2019.

Aarẹ Buhari nigba to n ba awọn igbimọ alaṣẹ ṣe ipade ni ọjọ aje ni Abuja, fi kun un wipe ohun yoo dije si ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2019.

Lara awọn ara ilu nigba ti wọn n ba BBC Yoruba s'ọrọ wipe igba ko lọ dede fun awọn, nitori naa ko yẹ ki aarẹ sọ wi pe oun n lọ fun saa keji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionArá ìlú f'èrò hàn lórí sáà kejì Bùhárí

Ṣugbọn awọn miran sọ wi pe saa keji yoo fun aarẹ naa laaye lati pari gbogbo iṣẹ to bẹrẹ ni saa kini rẹ.

Ninu ọrọ ti wọn, onimọ nipa eto oṣelu, Gbola Oba ati Kayode Eesuola sọ wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari lẹtọ labẹ ofin lati dije gẹgẹbi aarẹ lẹlẹẹ keji.

Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Ará ìlú f'èrò hàn lórí sáà kejì Bùhárí

Amọ, wọn fikun un wipe awọn ọmọ Naijiria ni yoo woye gbogbo bi eto oṣelu saa aarẹ Buhari ṣe ri lalakọkọ, ki wọn to pinnu lati d'ibo fun lelekeji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: