Kókó ìròyìn t'òní: Sáà kejì Ààrẹ Bùhárí, Ọlọ́pàá yìn'bọn lu akẹ́kọ̀ọ́ l'Óǹdó

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

Sáà kejì Ààrẹ Bùhárí: Àwọn ọmọ Nàíjíríà f'èrò wọn hàn

Àkọlé fídíò,

"Ẹ jẹ́ kí Buhari lọ jókòó"

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti fi ero wọn han lori bi Aarẹ Muhammadu Buhari se fi ipinnu rẹ han lati dije fun ipo aarẹ lẹlẹẹkeji ni idibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun 2019.

Aarẹ Buhari nigba to n ba awọn igbimọ alaṣẹ ṣe ipade ni ọjọ aje ni Abuja, fi kun un wipe ohun yoo dije si ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2019.

Ọlọ́pàá yìn'bọn lu akẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó

Oríṣun àwòrán, AAUN News Forum

Àkọlé àwòrán,

Owó ilé-ìwé tó kéré jù tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá n san tẹ́lẹ́ ni ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún lé ọgọ́rùn ún Náírà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Adekunle Ajasin, Akungba-Akoko tú síta kẹ̀tí-kẹ̀tí lónì''i láti fẹ̀hónú hàn lórí i àfikún owó iléèwé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Òndò paláṣẹ.

Ààrẹ fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ Òndó ní fásitì nàá, Popoọla Morayọ Samson sọ fún BBC pe ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó ṣèlérí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá láti fi tùwọ́n l'ójú. Ṣùgbọ́n, ó ní àwọn kò fẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nàá, ẹ̀dínwó owó ilé-ìwé l'àwọ́n fẹ́. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC:

Fidio wa fun toni:

Ọmọ́yelé Sòwòrẹ́ tó fẹ́ dupò ààrẹ ní Nàíjíríà ní òun kò leè bá jẹgúdújẹrá ẹgbẹ́ òsèlú APC àti PDP se pọ̀.

Àkọlé fídíò,

Sòwòrẹ́: Èmi kò leè bá jẹgúdújẹrá APC àti PDP se pọ̀