Fayose: Nàìjíríà kò nílò Buhari gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ rẹ̀ mọ́

Ààrẹ Bùhárí pẹ̀lú Gómìnà Fáyòṣé Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Bùhárí pẹ̀lú Gómìnà Fáyòṣé kò fìgbàkan ṣọ̀rẹ́ ara wọn

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, Ayọ̀délé Fáyòṣé ní, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò nílò Buhari gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ rẹ̀ mọ́.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lórí ìpinnu ààrẹ Bùhárí láti gbé àpótí ìbò lẹ́ẹ̀kejì, ni Fáyóṣé ti sọ èyí di mímọ̀.

Fáyòṣé ní, ' Bùhárí ti kùnà ní gbogbo ọ̀nà títí kan gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́ tó gbé karí.'

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ènìyàn tó tako Bùhárí ni Fáyòṣé jẹ́, kìí sìí tijú àti kọ lùú nígbà kúgbà tí ààyè rẹ̀ bá yọ.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ àwọn aṣíwájú orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni wọ́n ti ṣíwájú láti rọ Ààrẹ Bùhárí pé kó máse gbégbá ìbò ààrẹ lẹ́ẹ́kejì

Fáyòṣé ní ìjọba Buhari kò ṣe àǹfàní fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mọ àtipé ọ̀rọ̀ ìjọba Bùhárí ti sú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Fayose ní Bùhárí ti kùnà láti se àseyọrí ní gbogbo ẹ̀ka ìsèjọba

"A kò fẹ́ bàbá àgbà mọ́ nípò. Kò sí àṣeyọrí kan lẹ́ka ọ̀rọ̀ ààbò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka ọ̀rọ̀ ajé pẹ́lú mẹ́hẹ."

Lọ́jọ́ ajé ni ààrẹ Mùhámádù Bùhárí kéde rẹ̀ fáye pé, òun fẹ́ gbégbá ìbò sípò ààrẹ lẹ́ẹ́kejì eléyìí tó ti ń fa àríyànjiyàn láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà.