Fasiti OAU: À wádìí olùkọ́ tó fẹ́ bá akẹ́kọ̀ọ́ lò fún máákì

Ẹnu ìloro fásitì OAU Image copyright @OfficialOAU
Àkọlé àwòrán Fásitì OAU ní ààbò àṣírí wà fún akẹ́kọ̀ọ́ yóówù tó bá ta àwọn aláṣẹ fásitì náà lólobó ìwà ìbàjẹ́

Fásitì Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Ìlú Ilé ifẹ̀, OAU, ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ lórí ìròyìn aṣemáṣe tó dá lóríi ẹ̀sùn bíbéèrè fún ìbálòpọ̀ láti gba máàkì ìdánwò lọ́wọ́ akẹ́kọ́bìnrin kan, èyítí wọ́n fi kan ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ fásitì náà.

Ariwo ta lórí ìtàkùn ayélujára ní ọjọ́ ajé, nípa ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele, ti ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ìṣirò owó tí wọ́n ní, o ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ ìgbà máàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ́bìnrin tó fìdírẹmi nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kan tí ọ̀jọ̀gbọ́n náà ń kọ́.

Ohùn àkásílẹ̀ nípa àjọsọ ọ̀rọ̀ láàárín akẹ́kọ́bìnrin ọ̀hún àti ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ti wọ́n ká sílẹ̀ sórí ìkànnì ayélujára, ló tí ń jà ràìn-ràìn káàkiri báyìí.

Alukoro fásitì Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Ìlú Ilé ifẹ̀, OAU, Ọ̀gbẹ́ni Abíọ́dún Ọláńrewájú n,i fásitì náà ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀ tí wọ́n sì ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti tú'ṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò ọ̀rọ̀ náà.

Image copyright Facebook/@OfficialOAU
Àkọlé àwòrán Fasiti OAU: À wádìí olùkọ́ tó fẹ́ bá akẹ́kọ̀ọ́ lò fún máákì

Nínú ìfòròwánilẹ́nuwò rẹ̀ pẹ̀lù BBC Yorùbá, alukoro fásitì OAU ni àwọn aláṣẹ fásitì náà yóò ṣe ohun gbogbo tó bá tọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

OAU kò fààyè gba kí olùkọ́ fi tipá bá akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀

"A fẹ́ gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti wòó bóyá nǹkan tí a gbọ́ lórí ìkànnì ayélujára jẹ́ òòtọ́ tàbí irọ́. Tó bá wá jẹ́ òòtọ́, a óò gbé ìgbésẹ tí òfin ilé ìwé yìí là kalẹ̀."Ọ̀gbẹ́ni Abíọ́dún Ọláńrewájú ní fásitì OAU Ife kò fààye gba fífi tìpá tìkúùkù fẹ́ tàbí bá ọmọbinrin láṣepọ̀, "yálà látọ̀dọ̀ olùkọ́ sí akẹ́kọ̀ọ́ tàbí akẹ́kọ̀ọ́ sí akẹ́kọ̀ọ́."Ilé ìwé gíga fásitì OAU ní ààbò àṣírí wà fún akẹ́kọ̀ọ́ yóówù tó bá ta àwọn aláṣẹ fásitì náà lólobó ìwà ìbàjẹ́ lọ́gbà fásitì náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: