Kayode Ogundamisi sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n se ńpa àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí ní ìlú London
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ogundamisi: Ó sú ni bí wọ́n ṣe ńpa wa lókè òkun

Ẹ̀wẹ̀, ìJọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti fi àìdunú hàn sí bí wọ́n se ńpa àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí ní ìlú òyìnbó láì jìnà síra.

Lọ̀sẹ̀ yìí ni isẹ̀lẹ̀ míì tún sẹ̀ ní ìlú London tí ọ̀rọ̀ yìí sì ń kọ ìjọba orílẹ̀èdè Nàìjíríà lóminú. Látàrí èyí, olùgbaninímọ̀ràn àgbà fún ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Àbíkẹ́ Dábírí-Erewà gba àwọn ọmọ Nàìjíríà nímọ̀ràn láti sọ́ra kí wọ́n sì kó ara wọn níjanu ìwà ipá.

Nínú ọ̀rọ̀ kan tí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn Abdur-rahman Balógun sọ ní ọjọ́ ajé ní ìlú Abuja, Àbíkẹ́ ní bí pípa àwọn ọmọ Nàìjíríà lókè òkun se ń peléke síi pàápàá àwọn tó wà ní ìlú London ńdá ìpòruru ọkàn sílẹ̀.

Wọ́n fi ìròyìn sọwọ́ wípé ó lé ní àádọ́ta ènìyàn aláwọ̀dúdú pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ wípé yálà wọ́n gún lọ́bẹ tàbí yìinbọn bá ní sáà kínní ọdún 2018 ní ìlú London nìkan.

Lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti pa báyìí ní ìlú òyìnbó ní sáà kínní ọdún 2018 pàápàá ní ìlú London nìkan ni Olúwadámilọ́lá Ọdẹ́yingbó (ọmọ ọdún méjìdínlógún), Taofeek Làmídí (ọmọ ogún ọdún) àti Harry Uzoka (ọmọ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n).

Àwọn míì ni Rótìmí Ọ̀sínbàjò (ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n), Fola Odubiyi (ọmọ ọdún méjìdínlógún), Níyì Shode (ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún), Kelvin Odunuyi (ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún), Abraham Badru (ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n), Israel Ogunsola (ọmọ ọdún méjìdínlógún) àti àwọn isẹ̀lẹ̀ míì tí wọn kò fi sọwọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: