Buhari: Àì lè ṣe dáradára tó mi wà lọ́wọ́ àwọn aṣòfin àpapọ̀

Aworan Buhari

Oríṣun àwòrán, TWITTER/BASHIR AHMAD

Àkọlé àwòrán,

Buhari ní ìṣèjọba òun yóò túbọ̀ gbájúmọ́ ètò àbò, gbígbógun ti ìwà ìjẹkújẹ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti di ẹbi bi awọn akanṣe iṣẹ lori ohun amayedẹrun lorilẹede naijiria ṣe n falẹ labẹ iṣejọba rẹ ru sunkẹrẹ-fakẹrẹ awọn aṣofin apapọ lori bibuwọ lu abadofin iṣuna eyi to ni o n ṣe ọpọ akoba.

Ninu ọrọ to sọ lasiko to fi n gbalejo igbimọ awọn eekan ọmọ ipinlẹ Niger kan ni ile aarẹ, Aso rock villa to wa nilu Abuja, aarẹ Buhari ni awọn aṣeyọri iṣejọba oun lẹka ipese ina ọba, opopona ati oju irinna fun ọkọ oju irin waye lai naani awọn ifasẹyin to n waye latọdọ awọn aṣofin apapọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ti o ba gba awọn aṣofin apapọ ni oṣu meje lati buwọlu abadofin iṣuna, o yẹ ki aye ko yin wa fun awọn ohun ribiribi ti a ti gbe ṣe. Ko dun mọ mi ninu rara, mo si ti pe awọn adari ile asofin apapọ lori rẹ."

Gẹgẹ bi atẹjade kan lati ọdọ olubadamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Fẹmi Adeṣina ṣe sọ, aarẹ Buhari ni iṣejọba oun yoo tubọ gbajumọ eto abo, gbigbogun ti iwa ijẹkujẹ ati tita eto ọrọ aje ji fun alekun idagbasoke ati ilọsiwaju.

Lẹ́yìn ìkéde Buhari, ta ni yóò kojú rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ APC?

Ki ṣe ohun tuntun mọ pe aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari yoo du ipo aarẹ lọdun 2019.

Ikede naa jẹ́ ohun ti eniyan fẹ́ẹ̀ le ni ọpọ ti ń reti fún ìgbà pípẹ́.

Ni bayi tí ààrẹ ti wa ṣiṣo lójú eégún ọ̀rọ̀ náà, ibeere ti awọn oluwoye n beere ni pe: Ta ni yoo koju rẹ?

Ẹjẹ ka tibi pẹlẹbẹ mu ole jẹ ninu APC to jẹ ẹgbẹ to wa lori ijọba.

Awọn Gomina APC f Buhari

Ṣaaju ki Buhari to kede pe ohun yoo du ipo Aarẹ lẹkan si, awọn Gomina labe ẹgbẹ APC ti ni ki Buhari so ero ọkan re lori ipo aarẹ lọdun 2019.

Igbese yi jo wipe o se afihan isokan laarin awọn Gomina naa.

Ni kete ti Buhari kede pe ohun yoo du ipo Aarẹ, opo lara awọn Gomina naa ti'n kan sara si lori igbese naa.

Ṣugbọn ki se gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo tẹlorun wi pẹ ki Buhari nikan du ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kwankwansiya

Àkọlé àwòrán,

Lọdun 2015, Kwankwaso dije nibo abele APC sugbọn o fidiremi lọwo Buhari.

Ẹnu n kun Rabiu Musa Kwankwanso pupọ lori boya yoo du ipo Aarẹ lọdun 2019 .

Ko ti so boya ohun yoo du ipo aarẹ yala labe asia ẹgbẹ APC tabi ẹgbẹ miran.

Ti a ba woye pelu atimaaṣebọ rẹ̀ tẹlẹ ati awọn ipolongo ti awọn ololufe re nse lori ẹro ayelujara, o ṣe ṣe kí o du ipo Aarẹ pẹlu Buhari.

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI/GETTY

Àkọlé àwòrán,

Bukola Saraki ni Aarẹ ile asofin agba

Ninu akoso iṣejọba lorileede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki lo wa ni ipo kẹta.

Ọmọ bibi Ilorin , o ti figba kan jẹ Gomina ni ipinlẹ Kwara o si ni iriri pupọ gẹgẹ bi aṣofin.

Ọpọ lo ti n foju sii lara pe o ṣeeṣe ki o du ipo aarẹ.

Ko tii daju boya yoo jade labẹ aṣia APC lọdun 2019.

Ẹgbẹ alatako

Iye awọn to ti si wi pe awọn fe du Aarẹ to je alatako ti pọ̀ diẹ̀.

Ṣugbọn ninu ẹgbẹ alatako, PDP, Gomina Ayọdele Fayose nikan ni o ti kede ni gbangba pe ohun fẹ di Aare.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/AYO FAYOSE

Àkọlé àwòrán,

Ninu alatako ijọba Buhari, Gomina Ayo Fayose lo je gbajugbaja ju lọ

Atiku ko gbeyin

Oríṣun àwòrán, TWITTER/ATIKU ABUBAKAR

Àkọlé àwòrán,

Atiku Abubakar n na owo ife si awọn olori kakiri orilẹẹde Naijiria.

  • O se igbakeji Aarẹ ri
  • O wa lara awọn ti wọn du ipo Aarẹ pẹlu Buhari lọdun 2015
  • Odu ni ki s'aimo foloko
  • O ti kede pe ohun fe je Aarẹ lọdun 2019

Awọn ọdọ

La i pe yi ni awọn odo oludije miran kan naa yoju sugbọn ko ti daju ẹgbẹ ti won yoo dije labe rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter Garba/Durotoye/Sowore

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọdọ ni asiko to lati gba ijọba lọdọ awọn agba oloseelu

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: