Àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́: Ènìyàn 2000 ti kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ darandaran

awon obinrin ti ogun le kuro nilu awon Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Ìkọlù darandaran pa èèyàn 2000'

Ajọ ajafẹtọ kan lorilẹede Naijiria ti sọwipe o le ni ẹgbẹrun meji (2000) eniyan to ti ku ninu rogbodiyan laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ lati bi Osu Mejidinlogun lorilẹede Naijiria.

Ajọ naa ti orukọ wọn n jẹ "The Coalition on Conflict Resolution and Human Rights in Nigeria" ninu atejade kan to jade ni Ọjọ Ajẹ, sọ wi pe ọgọọrọ lọ si ti di alairile gbe ni tori isẹlẹ naa.

Gẹgẹbi ọrọ ajọ naa, iye eniyan to ku naa ni wọn fi lede lẹyin iwadii lori iye ẹmi to ti sọnu, dukia, ile ati ọna to ti bajẹ nitori aigbọraeniye laarin awọn agbẹ ati darandaran lẹkun gbungun ariwa orilẹede Naijiria to fi mọ Benue, Taraba, Plateau, Kogi ati ipinle Nasarawa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Opo eniyan ku ninu ikolu fulani darandaran nipinle Benue

Wọn fikun wipe awọn ọlọsa naa tun kopa ninu isẹlẹ naa, nipa kiko ohun ini awọn eniyan ti ọfọ ba see.

Ti a ko ba gbagbe, awọn ile isẹ ologun Naijiria ti ran ikọ wọn lọ si agbeegbe naa lati da wọ isẹlẹ naa duro, sugbọn ikọlu si n waye lawọn igberiko kookan lagbeegbe naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: