Kókó ìròyìn t'òní: 'Ẹ ṣọ́ra ní London', ‘Ìkọlù darandaran pa èèyàn 2000’
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Ìjọba Nàìjíríà kìlọ̀ ìṣọ́ra ní ìlú London
Oríṣun àwòrán, @abikedabiri
Abike Dabiri lon kede ikilo fun awọn ọmọ Naijiria ni ilu London
Ijọba orilẹede Naijiria ti kilọ fun awọn ọmọ ilẹ naa to wa ni ilu London lati ma a sọ ara se nitori iṣekupani to n waye lagbeegbe naa.
Oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ ilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa ni oun ibanujẹ lo jẹ fun oun bi awọn alawọdudu, paapaa awọn ọmọ Naijiria se n padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ni ilẹ Geesi kọ oun lominu.
Àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ni ènìyàn 2000 ti kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ darandaran
Ajọ ajafẹtọ kan lorilẹede Naijiria ti sọwipe o le ni ẹgbẹrun meji (2000) eniyan to ti ku ninu rogbodiyan laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ lati bi Osu Mejidinlogun lorilẹede Naijiria.
Ajọ naa ti orukọ wọn n jẹ "The Coalition on Conflict Resolution and Human Rights in Nigeria" ninu atejade kan to jade ni Ọjọ Ajẹ, sọ wi pe ọgọọrọ lọ si ti di alairile gbe ni tori isẹlẹ naa. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ rẹ ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí, Rashidi Ladoja wípé kí àwon ọmọ Nàìjíríà jẹ́ kí Ààre Bùhárí gbé àpótí ìbò wò, bóyá yóò borí.
Rashidi Ladoja: Ẹ jẹ́ kí Bùhárí gbá'pòtí ìbò, bóyá yóò borí