Olú Fálaè: Orúkọ àwọn jẹgúdújẹrá tí APC tẹ̀ jáde kò tíì pé

Olú Fálaè: Orúkọ àwọn jẹgúdújẹrá tí APC tẹ̀ jáde kò tíì pé

Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ nígbàkan, tó tún jẹ́ èèkàn olósèlú nínú ẹgbẹ́ òsèlú SDP, Olóyè Olú Fálaè ti ní Orúkọ àwọn jẹgúdújẹrá tí APC tẹ̀ jáde kò tíì pé tó.

Fálaè wá ń bèèrè pé sé kò si jẹgúdújẹrá rárá l‘ẹgbẹ́ APC ni, ni orúkọ wọn kò se sí nínú orúkọ àwọn jẹgúdújẹrá tí ìjọba ẹgbẹ́ APC tẹ̀ jáde.

Ó wá kéde pé ọ̀pọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ APC ni wọ́n ti fẹ̀sùn àjẹbánu kàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọn wa ní PDP, kí wọn tó ya lọ sí APC, ó sì yẹ kí wọn gbé orúkọ tiwọn náà síta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: