Olórí Asòfin Kwara: Ó ti bọ́ fún Bùhárí láti gbógun tìwà ìjẹkujẹ

Olórí Asòfin Kwara, Ọ̀mọ̀wé Alli Ahmad Image copyright Alli/Facebook
Àkọlé àwòrán Ahmad fi ìka hánu lóríi bí ìjọba àpapọ̀ se kùnà láti tu àwọn èèyàn ìlú Ọ̀ffà nínú

Olórí ilé asòfin ní ìpínlẹ̀ Kwara, Ọ̀mọ̀wé Alli Ahmad ti nàka àlèèbú sí ìjọba àpapọ̀ Nàíjíríà pé ó ti kùnà pátápátá láti se àseyọrí ní ìdí ogun tó ń gbé ti ìwà ìjẹkújẹ, tí kò sì mú ìlérí rẹ̀ sẹ nípa sísẹ́ eegun ẹ̀yìn ìwà jẹgújẹrá.

Ahmad kéde bẹ́ẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn akọròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Ìlọrin pẹ̀lú àfikún pé àsìse ńlá ni fún Bùhárí láti gbájúmọ́ ètò gbígbé ogun tìwà ìbàjẹ́ nìkan gẹ́gẹ́ bíi àfojúsùn ìjọba rẹ̀ nígbàtí ètò ìdájọ́ wa wọ́lẹ̀ ní Nàíjíríà.

"Ẹni tó pegedé jùlọ tí orílẹ̀èdè Nàíjíríà ní láti gbógun ti ìwà jẹgúdújẹrá láti ìgbà tí a ti gba òmìnira ní Bùhárí, sùgbọ́n ó ti pàdánù ànfààní náà, tí èmi kò sì lérò pé ó tún leè rí ọ̀nà míràn láti tún àsìse yìí se."

Bákannáà ni Ahmad tún fi ìka hánu lóríi bí ìjọba àpapọ̀ se kùnà láti tu àwọn èèyàn ìlú Ọ̀ffà àti ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara nínú lóríi ìkọlù àwọn adigunjalè àti ìpànìyàn tó wáyé ní Ọ̀ffà ní àìpẹ́ yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ni ìjọba àpapọ̀ tó sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ yìí, èyí tó ní ó da omi tútù sí àwọn lọ́kàn.

Máákì òdo ni Ahmad fún ìjọba àpapọ̀

"Ìsẹ̀lẹ̀ adigunjalè yìí ló fi ìdí iyèméjì àwọn èèyàn kan múlẹ̀ pé Bùhárí kò ní agbára tó láti mú ìrẹ́pọ̀ àti ìdúrósinsin bá orílẹ̀èdè Nàíjíríà ."

Ó fikúu pé máákì òdo ni ìjọba àpapọ̀ gbà nínú èyí, tó sì dun àwọn jọjọ́ púpọ̀.