INEC: Ẹgbẹ̀rún márùn ún náírà ni ìbò Òǹdó,Edo àti Anambra

Oludibo kan gbe patako Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán "Láàárín 2015 sí àsìkò yìí, ìdìbò ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́fà ni àjọ INEC ti ṣe nínú èyí tí wọ́n ti wọ́gilé méjìdínlọ́gbọ̀n"

Àjọ elétò ìdìbò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà, INEC, ti fẹ̀sùn kan àwọn olóṣèlú àtàwọn olólùfẹ́ wọn pé, wọ́n ń fi ìbò rírà pa ètò ìdìbò sípò Gómìnà lára ní ìpínlẹ̀ Edo, Ondo àti Anambra.Alága àjọ INEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu, ló sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó ń bá àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ sọ̀rọ̀ lórí ìdìbò sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, tí yóò wáyé lóṣù keje.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán INEC ní àjọṣepọ̀ tó rinlẹ láàárín àjọ náà àtàwọn agbófinró ni wọ́n yóò fi k'ápá ìbò rírà

Mahmood Yakubu, ti alákòóso fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Èkìtì, Ọ̀ṣun àti Òǹdó sojú fún, ṣàlàyé pé àjọṣepọ̀ tó rinlẹ ̀láàárín àjọ náà àtàwọn agbófinró ni wọ́n yóò fi k'ápá rẹ̀."Gbogbo rẹ̀ ló hàn sí àjọ yìí. Ẹgbẹ̀rún márùn ún náírà ni àwọn olóṣèlú san fún ìbò kọ̀ọ̀kan ní ìpínlè Òǹdó àti Anambra. A tilẹ̀ gba àwọn owó kan lọ́wọ́ àwọn kan nípínlẹ̀ Anambra, ṣùgbọ́n irúfẹ́ èyí kò ní wáyé ní ìbò Èkìtì."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán INEC ní àwọn ràbòràbò r'áyé jẹ lásìkò ìbò ní'pínlẹ̀ Edo, Ondo àti Anambra

Bákannáà ni àjọ INEC tún pariwo pé, àìkìí fààyè gba ètò ìṣèlú àwarawa abẹ́nú táwọn ẹgbẹ́ òṣèlú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà gùnlé, ń ṣe ọ̀pọ̀ àkóbá fún àṣeyọrí ìdìbò.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionINEC yoo sun miliọnu meje kaadi idibo

"Láàárín ọdún 2015 sí àsìkò yìí, ìdìbò ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́fà ni àjọ yìí ti ṣe nínú èyí tí wọ́n ti wọ́gilé méjìdínlọ́gbọ̀n nítorí àìkìí fààyè gba ètò ìṣèlú àwarawa labẹ́nú láàrin áwọn ẹgbẹ́ òṣèlú."Alága àjọ INEC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu, wá fi dá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Èkìtì lójú pé, àjọ náà kò ní ṣègbè lásìkò ìdìbò náà.