Àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ni Ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ̀wọ̀ akẹ́ẹ̀kọ́ kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀

Ẹnu ìloro fásitì OAU Image copyright @OfficialOAU
Àkọlé àwòrán Fásitì OAU ní ààbò àṣírí wà fún akẹ́kọ̀ọ́ yóówù tó bá ta àwọn aláṣẹ fásitì náà lólobó ìwà ìbàjẹ́

Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nílééwé fásitì OAU Ile-Ife, ni ariwo rẹ̀ ti gbòde kan báyìí pé ó bèèrè àti bà akẹ́ẹ̀kọ́ obìnrin lájọṣepọ̀ fún ìgbà máàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti fún ní máàkì.

Ní báyìí, àwọn aláṣẹ fásitì náà ti gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹni-márùn ún kalẹ̀ láti ṣèwaàdí sí ọ̀rọ̀ náà.

Ọ̀sẹ̀ kan ni ìgbìmọ̀ náà ní láti fi jábọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

Àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ kan tó ti kọjá ní fásitì náà ní ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe e.

Ọ̀kan lara awon akekojade ileewe naa to ti keko jade ni nkan bii ogun ọdún sẹyìn ni igba ti awọn ti wa nileewe naa ni ojogbon yìí ti bẹrẹ.

"Mo rántí ọkan lara àwọn orẹ mi nigba naa to n kaya soke lori pe Ọ̀jọ̀gbọ̀n Akindele dẹ̀nu ibalopọ̀ kọ̀ oun. O ni ki a maa ba oun gbadura.

Lẹyin ọpọlọpọ adura, ọjọgbọn yii ni oun ti yii skan oun pada lori rẹ.

Bakan naa ni iwadi fihan lati ọdọ awọn akẹkọ faisti naa pe ohun ọjọgbọn Richard Akindele lo wa ninu ohun ti wọn gba silẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics