Bùhárí: Ariwo ọmọ Nàìjíríà ló mú mi fẹ́ díje lẹ́ẹ̀kejì

Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí àti Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìjọ Anglican ní Canterbury, Ẹniọ̀wọ̀ Justin Welby Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Bùhárí ní òṣèlú ẹ̀tánú ló wà nì ìpìlẹ̀ wàhálà àgbẹ̀ àti darandaran,

Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí ti bọ́ síta láti ṣàlàyé ìdí rẹ̀ tòun fi kéde ìpinnu òun láti gbé àpótí ìbò ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì.

Nígbà tó ń gbàlejò Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìjọ Anglican ní Canterbury, Ẹniọ̀wọ̀ Justin Welby ní ìlú London. Buhari ní,

"Torí awuyewuye tó ń jà láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí bóyá màá díje tàbí n kò ní díje ló jẹ́ kí n kéde kí n tó kúrò ní Nàìjíríà."

"Omi ń bẹ láàmù fún wa lórí ètò àbò, ètò ọ̀gbìn, ọrọ̀ ajé, gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Kò yẹ kí òṣèlú ó jẹ́ ìdààmú fún wa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ̀tanú ló wà ní ìdí wàhálà darandaran

Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí tún ṣàlàyé àwọn àṣeyọrí ìjọba rẹ̀ fún ẹni ọ̀wọ̀ Welby.

Ó ní lórí wàhálà àgbẹ̀ àti darandaran, òṣèlú ẹ̀tánú ló wà nì ìpìlẹ̀ rẹ̀.

Bákannáà ni ààrẹ Mùhámádù Bùhárí ní àwọn ń mójú tó àtipadà wálé e Leah Sharibu, akẹ́kọ̀ Dapchi tó ṣì wà ní àhámọ́ àwọn Boko haram nítórí pé ó kọ̀ láti yípadà sí ẹ̀sìn Islam.