SERAP: Ọjọ́ méje la fún UI, AAUA lati dá owó iléẹ̀kọ́ padà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ̀hónú hàn nípìnlẹ̀ Òndó Image copyright AAUN News Forum
Àkọlé àwòrán Akitiyan BBC láti bá iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Òndó jásí pàbó

Àjọ ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn kan lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, SERAP ti ń lérí léka pé àwọn yóò gbé àwọn aláṣẹ fásitì Ìbàdàn, UI àti fásitì ìpínlẹ̀ Oǹdó lọ sí ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tètè tún èrò wọn pa lórí àfikún owó ilé ìwé

tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀.

SERAP fún àwọn aláṣẹ fásitì méjèèjì ní gbèdéke ọjọ́ méje làti fi dá owó ilé ìwé náà padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

'Ọ̀jọ̀gbọ́n Akindele kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa bèèrè fún ìbálòpọ̀'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkẹ́kọ̀ọ́ dókítà: Fásitì Ìbàdàn gbọdọ̀ dín owó iléẹ̀kọ́ wa

Àjọ náà ní àwọn yóò lo ìlànà òfin láti fi kàn án nípá fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ni yóò jókòó sílé nítorí èlé iléèwé

Nínú àtẹ̀jáde kan lọ́jọ́ọ̀bọ tí igbákejì ọ̀gáàgbà àjọ SERAP, Timothy Adéwálé fi síta, ọgbọ́n àti sé ọ̀nà ìmọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́ ni ìgbésẹ̀ àfikún owó iléẹ̀kọ́náà yóò padà jásí.

"Àìní leè san àfikún owó ilé ìwé yìí leè mú kí àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ó fi iléẹ̀kọ́ sílẹ̀ tí yóò sì leè ṣílẹ̀kùn ìṣòro ayérayé fún wọn."

Àkọlé àwòrán Àfikún owó ilé ìwé leè dákún ìsòro Nàíjíríà

Bákannáà ni àjọ SERAP tún ké sáwọn aṣòfin àpapọ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà láti gbé òfin kalẹ̀ láti dẹ́kun bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ṣe ń fowó kún owó wọn.

Àfikún owó ilé ìwé leè dákún ìsòro Nàíjíríà

Fásitì Ìbàdàn, UI gbé owó àkànṣe ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ f'áwọn akẹ́ẹ̀kọ́ rẹ̀ sókè láti ẹgbẹ̀rún márùndínláàdọ́ta, (75, 000) sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rún, (100, 000), tí owó iléègbé sì kúrò ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì, (40,000)

Fún fásitì ìpínlẹ̀ Oǹdó ní tirẹ̀, ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì làwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ń san tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó sún un sí ọgọ́fà ẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba.