Black Panther: Ọmọ Nàìjíríà gba àmì ẹ̀yẹ

Ṣọpẹ́ lásìkò tó n gba àmì ẹ̀yẹ Image copyright @sopealuko
Àkọlé àwòrán Ṣọpẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi òṣèré lẹ́yìn tó k'ẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ ẹ̀rọ.

Àwọn aláṣẹ agbègbè Miami-Dade, nílùú Florida, l'órílẹ̀èdè Àmẹ́ríkà ti fi àmì ẹ̀yẹ dá ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí ìlẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì tún jẹ́ òṣèré, Ṣọpẹ́ Àlùkò lọ́lá.

Wọ́n ṣeya ọjọ́ kẹwà, oṣù kẹrin sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bi ọjọ́ tí wọn yóò maa mọ rírì rẹ̀ fún ipa tó kó nínú sinimá Black Panthers.

Òṣèrébìnrin nàá t'ínú rẹ̀ dùn fi ìkéde nàá síta lójú òpó Instagram rẹ̀, ó ní ''Èyí ṣẹ̀sẹ̀ ṣẹlẹ̀!!!! Wọ́n fi àmì ẹ̀yẹ dámilọ́lá.

"Wọ́n sì ke'de ọjọ́ kéde Àyájọ́ Ọjọ́ Ṣọpẹ́ Àlùkò."

Ìkéde nàá jáse lẹ́yìn oṣù kan tí Ṣọpẹ́ f'ọwọ́ sí ìwé láti kópa nínú sinimá 'Venom' tí yòó jáde l'ọ́jọ́ karùn ún, oṣù Kẹwà, láti iléeṣẹ́ Marvel, nínú èyí tí Tom Hardy nàá ti kópa.

Image copyright @Sopealuko
Àkọlé àwòrán Ó tún ti kópa nínú sinimá bí Identity Thief, Pitch Perfect, 96 Minutes àti Grass Stains.

Ṣọpẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi òṣèré lẹ́yìn tó k'ẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ ẹ̀rọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: