Èkìtì 2018: Káyòdé Fáyemí f'èròhàn láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀

Kayode Fayemi Image copyright @kfayemi
Àkọlé àwòrán Kayode Fayemi yoo dupo pelu awon eeniyan mẹẹdọgbọn si ipo

Minisita fun ohun alumọni ilẹ lorilẹede yii, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti ṣe afihan ipinnu rẹ si awọn olori ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati awọn gomina labẹ ẹgbẹ naa lati dupo gomina ipinlẹ Ekiti ninu idibo ọjọ kẹrinla, oṣu keje 14 ni ipinlẹ naa.

Ọgbẹni Fayemi, ti o jẹ gomina ana ni Ipinle Ekiti, sọ ni ọjọbọ lẹyin abẹwo akanṣe si awọn agbegbe ati ijọba ibilẹ ni Ekiti.

Atẹjade kan lati ọwọ oluranlọwọ̀ ati agbẹnusọ re, Yinka Oyebode, sọ wipe Minisita naa yoo ṣe ikede ipinu lati gbe'gba ibo fun ipo gomina ipinlẹ naa ni ọjọ abamẹta.

Gegebi ọ̀rọ̀ naa, ọgbẹni fayẹmi ti kọ lẹta ranṣẹ si alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Oloye John Oyegun; adari apapọ ẹgbẹ APC, Asiwaju Bola Tinubu; Oloye Bisi Akande; gbogbo awọn olori ibilẹ ni Ipinle Ekiti; awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ni ile igbimọ alaṣẹ apapọ (FEC); awọn oludari ati awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ati awọn ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọwe Fayẹmi ni ere ọmọde ni igbesẹ ijọba fayose lati fofin de oun

Ọgbẹni Oyebode sọ pe Minisita naa ti ṣe ipade pẹlu awọn ijọba agbegbe ibilẹ ati awọn alagba igbimọ ati awọn alàgba ẹgbẹ lakoko irin ajo rẹ si awọn agbegbe ijọba ibilẹ mẹrindinlogun naa.

Abẹwo naa bẹrẹ ni ọjọ aje ni ijọba ibilẹ Efon, ti o si wa sopin ni ijọba ibilẹ Oye lọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: