Kókó ìròyìn t'òní: Káyòdé Fáyemí fun Èkìtì 2018, owó iléèwé UI, AAUA

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti oni.

Ekiti 2018: Kayode Fayemi f'ero han lati dupo gomina ipinlẹ

Oríṣun àwòrán, @kfayemi

Àkọlé àwòrán,

Kayode Fayemi yoo dupo pelu awon eeniyan mẹẹdọgbọn si ipo

Minisita fun ohun alumọni ilẹ lorilẹede yii, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti ṣe afihan ipinnu rẹ si awọn olori ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati awọn gomina labẹ ẹgbẹ naa lati dupo gomina ipinlẹ Ekiti ninu idibo ọjọ kẹrinla, oṣu keje 14 ni ipinlẹ naa.

Ọgbẹni Fayemi, ti o jẹ gomina ana ni Ipinle Ekiti, sọ ni ọjọbọ lẹyin abẹwo akanṣe si awọn agbegbe ati ijọba ibilẹ ni Ekiti.

SERAP: Ọjọ́ méje la fún UI, AAUA lati dá owó iléẹ̀kọ́ padà

Àjọ ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn kan lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, SERAP ti ń lérí léka pé àwọn yóò gbé àwọn aláṣẹ fásitì Ìbàdàn, UI àti fásitì ìpínlẹ̀ Oǹdó lọ sí ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tètè tún èrò wọn pa lórí àfikún owó ilé ìwé

tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀.

SERAP fún àwọn aláṣẹ fásitì méjèèjì ní gbèdéke ọjọ́ méje làti fi dá owó ilé ìwé náà padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Awon Fidio wa fun toni

Ǹjẹ́ ìwọ mọ kọ́mú tí wọn ń pè ní foamless, spacer, plunge, strapless, backless àti clap in front?

Àkọlé fídíò,

Àwọ̀tẹ́lẹ̀: Èwo lo ní ìfẹ́ sí nínú orísirísi kọ́mú yìí?

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Adekunle Ajasin, Akungba-Akoko fẹ̀hónú hàn ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Àkọlé fídíò,

Àgbáríjọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ AAUA fẹ̀hónú hàn nípìnlẹ̀ Èkó