Fáyòṣe fèsì lórí bí Buhari se ńdá Gaddafi lẹ́bi wàhálà darandaran

fayose ati Buhari n bọwọ Image copyright Nigeria presidency
Àkọlé àwòrán Fayoṣe ni awọn darandaran ti ko pa awọn ọmọ ilẹ̀ Libya ni wọn ń wá pa àwọn èèyàn ní Nàìjíríà.

Gómìnà Ayọ̀délé Fáyóṣe ti ìpínlẹ̀ Èkìtì ti sọ pé ìdójútì ńláǹlà ni Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí ń fún orílẹ̀èdè Nàìjíríà pẹ̀lú bí ó ṣe lọ ń di ẹ̀bi gulegule àwọn darandaran lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ru Ààrẹ Gaddafi ti ilẹ̀

Libya tó ti di olóògbé .

Nínú àtẹ̀jáde kan tí oludari eto iroyin fun Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì náà, ọ̀gbẹ́ni Lere Olayinka fi síta, Fáyóṣé ní " ìtìjú ń lá ló jẹ́ pé ààrẹ tún gbé àṣà kó máa di ẹ̀bi ru gbogbo èèyàn dé àwùjọ àgbáyé dé ibi pé ó tún ń di

ẹ̀bi ru ẹni tó ti jáde láyé."

Ààrẹ Bùhárí sọ, nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lu Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìjọ Anglican ní Canterbury, Ẹniọ̀wọ̀ Justin Welby ní ìlú London, pé ààrẹ orílẹ̀èdè Libya, Moumah Ghadafi tó kú ní ọdún méje sẹ́yìn ló kó ohun ìjà olóró fún

àwọn ọmọlẹyìn rẹ̀ tí wọ́n ti wá ṣàn wọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n Fáyóṣé ní kí ààrẹ Mùhámádù Bùhárí ó gbájúmọ́ ìpèníjà tó ńkojú ìjọba rẹ̀ láti pèsè ààbò tó péye fún àráàlú dipo didi ẹ̀bi gbogbo ìjákulẹ̀ rẹ̀ ru ẹnikẹni to ba ri lọ̀.

O ni bawo lo ṣe jẹ́ pé awọn darandaran ti ko pa awọn ọmọ ilẹ̀ Libya ni wọn ń wá pa àwọn èèyàn ní Nàìjíríà.

"Awọn ọmọ orilẹede Naijiria n di ẹbi ru aarẹ Buhari ati ijọba rẹ̀ pé wọn lọwọ ikọ̀lu awọn darandaran lorilẹede yii, ṣugbọn ohun ti aarẹ ri lati fi fesi si ẹhonu araalu ni ko di ẹ̀bi ru Ghadaffi to di oku ni ọdun meje

sẹyin.

Ìtìjú agbami agbaye ni eleyii lati ọwọ aarẹ ti ko mọ̀ ju ki o maa di ẹbi gbogbo ijakulẹ rẹ̀ ru ẹlomiran lọ.