Owó tí Àbáchà jí: Wo ohun tí ó lè ṣe fún ará ìlú

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ijọba orileede Switzerland ti da ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin milionu dollar pada ninu owo naa laarin odun mewa seyin.

Ti o ba gbiyanju lati fi ẹrọ iṣiro rẹ tẹ milionu ọ́ọ́dúnrún le méjilelogun dollar ($322.5million dollars) ni iṣiro owo Naijiria elo lo ro wipe yoo je?

Ẹro isiro re'n gbẹko abi?

Ma se wahala jina, a ti ba o te.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Owo tabua ni owo ti ọgagun Abacha fi iye ọdun to wa ni ijọba ko

116,100,000,000.00 to je bilionu mẹ́rìndínlọ́gọ́fà ati ogorun milionu naira lo je.

Eyi ni iye owo ti ijọba apapo kede laipe yi pe awọn ri gba pada lọdun 2017 lati ọdọ ijọba orileede Switzerland ninu owo ti Aarẹ orileede Naijiria nigba kan ri ọgagun Sani Abacha ji pamọ.

Ṣugbọn awuyewuye po lori owo naa paapa julo lori iye ti awọn agbẹjoro fẹ gba gẹgẹ bi owo ise fun pe wọn se atọna dida owo naa pada.

Orisun owo naa

  • Luxembourg ni wọn ni Abacha ko owo naa pamo si.
  • Wọn fura si wi pe o wa lara owo ti ọgagun Sani Abacha ji laarin ọdun 1993 si 1998
  • Aare Muhammadu Buhari mu gbigba owo yi pada gẹgẹ bi koko ileri rẹ lasiko ipolongo ibo lọdun 2015
  • Ile isẹ eto idajọ, Banki agbaye ati orileede Switzerland fi ọpọ asiko jiroro lati se agbekalẹ eto fun dida owo naa pada fun orileede Naijiria
  • Ijọba orileede Switzerland ti da ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin milionu dollar pada ninu owo naa laarin ọdun mẹwa sẹyin
  • Milionu ọ́ọ́dúnrún le méjilelogun dollar ($320million) ni owo to sẹku ti wọn da pada

Kini owo naa le se fun ara ilu.

Bi ẹ ba fi ọkan si iye odo to wa lẹyin biliọnu 116,100,000,000.00 ọrọ na ko le ye yin daada.

Ẹ jẹki a se akawe awọn nnkan ti owo naa le se fun ara ilu.

Bukata owo Sukuk

Se ẹ ranti owo Sukuk ti ijọba apapo ya laipe yi lati fi pari awọn oju ọna kan kakiri orileede Naijiria?

Image copyright TWITTER/KEMI ADEOSUN
Àkọlé àwòrán Oju ọna mẹẹdogbọn ni ijọba fẹ fi owo Sukuk se atunse wọn

Ijọba apapọ ni ọgorun billionu (100 billion Naira naira) ni apapọ owo naa je.

Lara awọn oju ọna ti wọn gbe jade pe awọn fẹ tun se ninu owo na to kan ilẹ Yoruba lati ri:

  • N5,666,666,666.67 fun oju ọna marose ibadan si Ilorin,abala keji oju ona Oyo Ogbomosho ni ipinle Oyo
  • N5,000,000,000.00 fun atunse apa kan oju ọna onibeji Benin-Ofusu-Ore-Ajebandele-Shagamu ati
  • N6,000,000,000.00 fun atunse ati dida ọda oju ọna onibeji Benin-Ofosu-Ore-Ajebandele-Shagamu

Apapọ awọn owona wọnyii (16.6 billion naira ) ko ti ni ipa gbogi lara biliọnu 116,100,000,000.00 owo Abacha ti a gba pada o!

Se ẹ ri wipe owo naa ki se owo die?

Ki lo ku ti a le fi se?

Nnkan ti owo naa le se pọ.

Fun apere owo naa le san owo ipin osoosu ti ipinlẹ Osun n ri gba ninu akoto owo ijọba apapọ lati osu yi titi di ipari ọdun 2018.

Image copyright NBS NIGERIA
Àkọlé àwòrán Owo ipin osoosu ti ipinle Osun ti ajo to'n risi ounka oun isiro

Sibẹ sibẹ owo naa yoo sẹku.

Ni ẹka eto ẹko, ipese ina ọba, sisan owo osisẹ ati dida abo bo ilu, owo naa le ni ipa ti yoo ko.

Ohun to ku bayi ni ki ijọba se amojuto nina owo naa fun anfaani ara ilu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè nífẹ̀ síí: