Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun kéde ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti gba káàdì ìdìbò

Káàdì ìdìbò alálòpẹ́ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ÌJọba ìpínlẹ̀ Ọ̀sun kéde ọjọ́ ajé tó mbọ̀ láti gba káàdì ìdìbò

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ti kéde ọjọ́ ajé ọ̀sẹ̀ tó mbọ̀ ìyẹn ọjọ́ kẹrìndídínlógún, oṣù kẹrin fún àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ náà kí wọ́n lèè kópa nínú gbígba káàdì ìdìbò alálòpẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́.

Kọmíṣánà fún ọ̀rọ̀ abẹ́nú ní ìpínlẹ̀ náà, ọ̀mọ̀wé Ọbáwálé Adébísí, nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó sọ ní ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ nílu Òṣogbo sọ wí pé ìsinmi náà wà láti pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní fún àwọn tó tó dìbò láti kópa nínú ìgbésẹ̀ náà.

Adébísí rọ àwọn tí kò tíì forúkọ sílẹ̀ láti lo àkókò ìsinmi yìí láti se bẹ́ẹ̀ kí àwọn tó sì ti forúkọ sílẹ̀ lo ànfàní náà láti gba káàdì ìdìbò wọn.

APC bori ninu idibo nipinlẹ Ọsun

Ewu n bẹ ninu ki osisẹ oba s'oselu - Gbade Ojo

Ìforúkọsílẹ̀ àwọn olùdìbò àti gbígba káàdì ṣe pàtàkì fún ìlànà ìdìbò bẹ́ẹ̀ sì ni ó ní ipa tí ó ń kó nínú ìsèjọba àwa ara wa, ó ma ń músẹ́ yá nínú ìlànà ìdìbò àti ìsèjọba àwa ara wa.

Nítórí ìdí èyí ni ìjọba se ríì ní pàtàkì láti pèsè ànfàní tó yẹ nípa kíkéde ọjọ́ ajé gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi tó sì jẹ́ ọjọ́ àsekágbá fún àwọn tó tó dìbò láti f'orúkọ sílẹ̀.