Ọwọ́ sìkùn ọba tẹ lára àwọn afurasí tó kọlu ilú Òffà

Afurasí Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ lára àwọn afurasi tó kọlu ilú Òffà

Látarí ikọ̀lù tó wáyé láìpẹ́ nílu Ọ̀ffa, Iléeṣé ọlọ́pàá ti ìpinlẹ Kwara ti mú àwọn afurasí méjìlá míì tó ní se pẹ̀lú ìkọlù ilú náà láìpẹ́.

Ìròyìn tó ni létí wípé àwọn ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ọlọ́pàá alágbára ló kó àwọn afurasí apànìyàn náà.

Ikọ̀ ọlọ́pàá tó ní ǹkan ìjà, ìsọ̀rí mẹ́ta ọlọ́pàá àti àwọn irinsẹ́ amólè ni ọ̀gá àgbà pátápátá àwọn ọlọ́pàá kó ráńsẹ́ sí ìpinlẹ Kwara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒkú sùn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè ní Ọ̀ffà

Kí ní ńǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Ọ́ffà

Ìlú Ọ̀ffà ní ìpínlẹ̀ Kwara wárìrì lọ́jọ́bọ, tí kowéè ké láì ha, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè kan tó wáyé nílé ìfowópamọ́ márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú náà.

Àwọn eeṣin kò kọ ikú adigunjalè náà, tí wọ́n tó ọgbọ̀n níye ló ṣe ọṣẹ́ láwọn báńkì náà fún wákàtí méjì àti ààbọ̀ gbáko, èyí tó sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di opó àti ọmọ òrukàn.

Kí aráyé baà leè mọ̀ pé eré kọ́ làwọn wá ṣe, àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Owódé làwọn alọkólóhunkígbe yìí ti kọ́kọ́ kí wọn kú ilé níbẹ̀, tí wọ́n sì rán àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́, àwọn èèyàn tó ní ẹjọ́ ní tésàn náà àtàwọn èèyàn míì tó wà níbẹ̀ sọ́run ọ̀sángangan.

Image copyright Ayobami Agboola
Àkọlé àwòrán Guaranty Trust Bank Offa, Kwara state

Agbẹnusọ fún olú iléeṣé ọlọ́pàá, Jimoh Moshood sọ pé wọ́n gba àwọn ǹkan bíi ẹ̀rọ alágbeká, ẹ̀rọ àtẹ́léwọ́ ipad àti káàdì ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n fara gbá padà lọ́wọ́ wọn.

Nínú àwọn báǹkì ilú Ọ̀ffa ni àwọn adigunjalè yìí tí sọsẹ́ sùgbọ́n ibi tí ọwọ́ ti tẹ̀ wọ́n ni ilú Èkó, Ìbàdàn, Ìlọrin àti Ọ̀ffa pẹ́lú àwọn ǹkan ìjà olóró bíi ìbọn gbúntú alágbára àti àwọn ọta ìbọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Ara fu mí nígbàtí bàbá gbé Bíbélì ìdílé fúnmi’

Related Topics