APC- àjòjì ọkùnrin kan gbàsàkóso iìkànì Twitter rẹ̀

Àwòrán Twitter APC Image copyright Twitter.com/APC
Àkọlé àwòrán APC kò tíì sàlàyé oun to sẹlẹ̀

Arakunrin kan, Justin Sun ni o ti gbàsàkóso ìkànì Twitter ẹgbẹ oselu APC lọ́jọ́ ìsinmi.

Oun ti a sàkíyèsí ni pe, níse ni àsíá ẹgbẹ oselu APC to wà lori ikani ọun yípadà si ti ọ̀gbẹ́ni Sun yii, ti ó sì n kọ orisirisi nnkan nipa ijọba orilẹede Naijiria.

Okunrin ọun sọ̀rọ̀ nipa pe ijọba Naijiria n pín owó orí ẹ̀rọ ayélujára ti a mọ̀ sí Bitcoin.

Bákan náà lo tún sọ nipa àjọ INEC. O ni irọ́ pata ni pe INEC n gba awọn eniyan sísé fun ìdìbò 2019.

Image copyright TWiotter.com/APC
Àkọlé àwòrán Orisirisi a[rà ni Sun n da lori ìkànì Twitter ẹgbẹ́ oselu APC

Egbẹ APC ko tii fọhùn rárá lori ọ̀rọ̀ naa.