Gold coast 2018: Nàìjíríà ní góòlù mẹ̀sán láti dúró ní ipò kẹsán

Bí ìdíje àwọn orílẹ̀èdè tó ti fìgbàkan rí wà lábẹ́ ìmúnisìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Commonwealth ṣe ń wá sí ìdádúró lọ́jọ́ àìkú, orílẹ̀èdèNàìjíríà ti bọ́ sí ipoò kẹsán lórí atẹ ìgbéléwọ̀n àmì ẹ̀yẹ níbi ìdíje náà.
Goolu mẹsan, fadaka mẹsan ati baaba mẹfa ni awọn oludije lati orilẹede Naijiria ti gba bayii.
Ere asafogi ọlọgọrun mita fawọn obinrin, Women's 100m Hurdles, ere asadiju ọlọgọrun mita fun awọn akanda, irin gbigbe ati ijakadi ni orilẹede Naijiria ti gba ami ẹyẹ goolu.
Ipò | Orílẹ̀-èdè | Góòlù | Fàdákà | Bààbà |
Ikini | Australia | Ọgọ́rin (80) | Mọkandinlọgta (59) | Mọkandinlọgta (59) |
Ikeji | England | Marundinlaadọta (45) | Marundinlaadọta (45) | Mẹrindinlaadọta (46) |
Ikẹta | India | merindinlọ̀gbọ̀n (26) | Ogun (20) | Ogun (20) |
Ikẹrin | Canada | Marundinlogun (15) | ogoji (40) | mẹtadinlọgbọn (27) |
Ikaarun | New Zealand | Marundinlogun (15) | Mẹrinndinlogun (15) | Marundinlogun (15) |
Ikẹfa | South Africa | Mẹtala (13) | Mọkanla (11) | Mẹtala (13) |
Ikeje | Wales | Mẹwa (10) | Mejila (12) | Mẹrinla (14) |
Ikẹjọ | Scotland | Mẹsan (9) | Mẹtala (13) | Mejilelogun (22) |
Ikẹsan | Nàìjíríà | Mẹsan (9) | Mẹsan (9) | Mẹfa (6) |
Ikẹwaa | Cyprus | Mẹjọ (8) | Ọkan (1) | Marun (5) |
Orilẹede Australia lo n lewaju atẹ igbelewọn naa pẹlu ọgọrin goolu, ilẹ Gẹẹsi tẹlee pẹlu goolu marundinlaadọta ti India si ṣe ipo kẹta pẹlu goolu mẹrindinlọgbọn.
Orilẹede South Africa lo moke julọ laarin awọn orilẹede to wa lati ilẹ Afrika nibi idije naa pẹlu ami goolu mẹtala ti Naijiria si ṣe ipo keji.
Orilẹede Kenya lo ṣe ipo kẹta laarin awọn orilẹede Afrika nibẹ pẹlu ami goolu mẹrin.