APC kéde ìkànì ẹ̀rọ ayélujára tuntun

APC Image copyright Twitter.com
Àkọlé àwòrán Ikanni Twitter naa ní àmì ìdánilójú pe APC lo nií

Lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ to wáyé lọ́jọ́ abamẹ̀ta, nigba ti ọkunrin àjòjì kan gbàkóso ikani Twitter ẹgbẹ́ oselu APC, ẹgbẹ́ ọun kede pe, oun ti ni awọn ìkànnì ìbáraẹni sọ̀rọ̀ tuntun lori ẹ̀rọ ayélujára.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ pe ẹgbẹ́ APC ni ikanni ìbáraẹni sọ̀rọ̀ lori Twitter tẹ́lẹ̀, ẹgbẹ́ ọun sọ pe ikanni ọun kii se tàwọn, ati pe, awọn o ni ounkóhun se pẹlu ikanni ọ̀un ti o ni àdírẹ́ẹ̀sì @APCNigeria.

Ikanni yii ní oun tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́na ọgọ́rùún meje olùtẹ̀le, ti wọ̀n si ti síi lati ọdun 2013.

Ikanni Twitter ọun ni àmì ìdánilóju pe ẹgbẹ APC lo nií lọ́ọ̀tọ́, kó tó di pe wọn bẹ̀rẹ̀ si ni fi ikanni naa polówó òwò ẹ̀rọ ayelujara ti a mọ̀ sí Bitcoin lálẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta.

Àkọlé àwòrán Ikanni Twitter APC n polówó Bitcoin

Ni ọjọ́ ìsinmi ni agbẹnusọ ẹgbẹ APC Bolaji Abdullahi fi àtẹ̀jáde kan síta pe, awọn ti polongo lai mọye ìgbà pe ẹgbẹ APC kò ní ounkóhun se pẹlu ikanni Twitter yii, ati pe awọn rí oun to sẹlẹ̀ yii gẹ́gẹ́ bi iwa ọ̀daràn to lágbára.

Ninu àtẹ̀jáde ọ̀ún ni Abdullahi tun ti sọ pe ẹgbẹ́ APC ti sí awọn ìkanni tuntun ti yoo fun awọn olólùfẹ́ wọn, awọn oníròyìn ati gbogbo eniyan lapapọ̀ ní ooreọ̀fẹ́ lati mọ oun to n lọ ninu ẹgbẹ́ òsèlú ọ̀ún.

Awọn ìkànni ìbáraẹni sọ̀rọ̀ tuntun ti ẹgbẹ́ ọ̀ún fi síta nìyí:

Website: www.officialapcng.com

Twitter: https://twitter.com/OfficialAPCNg

Facebook: https://web.facebook.com/officialapcng/

Instagram: https://www.instagram.com/officialapcng/

YouTube: Official APC Nigeria