Balarabe Musa: Olè níkan ló leè jẹ ààrẹ Nàíjíríà

Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kàdúná, Balarabe Musa Image copyright Twitter/Onome Igugu
Àkọlé àwòrán Ẹnikẹ́ni kò leè jẹ ààrẹ Nàíjíríà bí onítọ̀ún kò bá kọ́kọ́ jalè tàbí káwọn olè tìí lẹ́yìn

Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kàdúná, Balarabe Musa ní kò sí ẹnikẹ́ni tó leè jẹ ààrẹ Nàíjíríà bí onítọ̀ún kò bá kọ́kọ́ jalè tàbí kí àwọn olè tìí lẹ́yìn.

Ó ní, kò sí bí ẹnikẹ́ni tó leè kó owó tó pọ̀ bíi èyí jọ fún ìpolongo ìbò ààrẹ lọ́nà tó tọ́ ní orílẹ̀èdè yìí.

Ó wa di ẹ̀bi ètò ọrọ̀ ajé àti ìgbáyé-gbádùn wa tó dagun ru ìlànà ètò òsèlú wa níbi tó ti jẹ́ pé ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rùn ùn nínú ọgọ́rùn ún àwọn asaájú tó wà nípò àsẹ ló jẹ́ olè

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Balarabe Musa, ẹni tó kéde bẹ́ẹ̀ nínú fọ́nrán àwòrán kan tó gba ojú òpó ìkànsíraẹni Facebook kan, bó ọ̀rọ̀ náà lójú tòró, nígbà tó ń gbàlejò olùdíje kan fún ipò ààrẹ, Ọmọyẹlé Sòwòrẹ́.

Bóyá ni yóò tó ìdá kan nínú olósèlú tí ọwọ́ wọn mọ́

Musa ni "Kínni àbùdà rere àwọn asaájú wa? lẹ́yìn sáà ìsèjọba olósèlù kejì, báwo ni yóò ṣe ṣeéṣe fún wa láti ní ìsọ̀rí àwọn aṣaájú tí kò níí jẹ́ olè? Kódà mò ń siyèméjì pé bóyá ni yóò tó ìdá kan nínú wọn tí ọwọ́ wọn mọ́, ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ ọ̀fọ́n ọ̀n pọ́núnbélé."

Gẹ́gẹ́ bí Balarabe Musa ti wí, èyí kò rí bẹ́ẹ̀ láyé ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́ẹ̀kejì, tó sì mú u wá sí ìrántí pé Shehu Shagari di ààrẹ Nàíjíríà láì jẹ́ olè.