Aisha Buhari: Torí òtítọ̀ ni mo fi sọ̀rọ̀ tako ọkọ mi

Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, Aisha Buhari Image copyright @aishambuhari
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari ní ìfẹ́ ìdájọ́ òdodo ti òun ní ló fàá tí òun fi ṣe bẹ́

Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, Aisha Buhari ti sọ ìdí tó fi sọ̀rọ̀ tako ọkọ rẹ, Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí̀ lórí ìṣèjọba rẹ̀ láwọn àkókò kan sẹ́yìn.

Aisha Buhari ní ìfẹ́ ìdájọ́ òdodo ti òun ní ló fàá tí òun fi ṣe bẹ́ẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí ayẹyẹ ìfàmì ẹ̀yẹ dánilọ́lá tí ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣe nílùú Èkó, ni ìyàwó ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà ti sọ èyí di mímọ̀.

"Kìí ṣe àfojúdi rárá. A kọ́ mi láti máa dìde jà fún òtítọ́, nítorí náà ni mo fi se bẹ́ẹ̀"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àmọ́ṣá, Aisha Buhari ní, níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ẹni ò ní ṣèdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀, ká fi ìlẹ̀kẹ̀ sídí ọmọ ẹlòmíràn, digbí lòun wà lẹyìn ọkọ òun nínú ìpinnu rẹ̀ láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìṣèjọba rẹ̀ fún sáà kejì.

Bí a ko bani gbagbe, Aisha ti fìgbàkan rí sọọ ́lórí BBC Hausa pé, bí nǹkan ṣe ń lọ nígbà náà kò bá yí padà, òun kò ní polongo ìbò fún ọkọ òun mọ́.