Ọbásanjọ́: Àwọn ọ̀dọ́ kò gbọdọ̀ dìbò fún Bùhárí

Ààrẹ Nàìjíría nígbà kan rí, Olúṣẹgun Ọbásanjọ́ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ́básanjọ́ tí ké pe Ààrẹ Bùhárí kó jọ̀wọ́ ìpinnu rẹ̀ láti gbe àpótí fún sáà kejì

Ààrẹ Nàìjíría nígbà kan rí, Olúṣẹgun Ọbásanjọ́ àti akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tẹ́lẹ̀, Olóyè Olú Fálaè, ṣe'pàdé bòǹkẹ́lẹ́ lórí ọ̀rò Ààrẹ̀ Muhammadu Buhari ní ọjọ́ Iṣẹ́gun.

Ìpàdé náà wáyé lẹ́hìn ọdún mọ̀kàndínlógún tí Obasanjo àti Falae ti ṣe àtakò ara wọn lórí ìbò ààrẹ l'ọ́dún 1999.

Àwọn èèkàn olósèlú bíi Doyin Okupe tó jẹ́ agbenusọ fún ààrẹ àná, Goodluck Jonathan àti olùdíje fún ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, lábẹ́ asia ẹgbẹ́ PDP, Gboyega Isiaka, wà ní ìpadé náà pẹ̀lú.

A gbọ́ wípé Fálaè, tó jẹ́ alága ẹ́gbẹ́ Social Democratic Party, SDP àti Ọ́básanjọ́ ti pinnu láti mú gbogbo àwọn alátakò sábẹ́ àsía kan ṣoṣo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ́básanjọ́, tó ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti kó àwọn ẹgbẹ́ alátakò bíi ọgbọ̀n mọ́ra, tún ti késí àwọn ọ̀dọ́ pe ki wọ́n maṣe dìbò fun Ààrẹ Buhari nítorí àìṣe dáadáa tó.