Maiduguri: Ènìyàn 380 ní àìsàn onígbàméjì ń bá fíra-Kọ́misọ́nà ilera

Alaisan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ààrùn onígbá méjì mú ẹmí ènìyàn mẹ́rìnlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Borno tí fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé ó kéré tán, ènìyàn mẹ́rìnlá ni ààrùn onígbá méjì ti gba ẹmí wọn ní ìpínlẹ̀ náà.

Haruna Mshellia tó jẹ́ kọmisọnà fún ètò ìlera, ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Maiduguri lọ́sàn òní.

O ní àwọn tí tójú àwọn ènìyàn ààdọ́talénígbà tí wọn fòjú hàn ní ilé ìwòsàn, tí àwọn ogúndínirínwó míràn sì wà lórí àkéte àìsàn

Ààrùn yínrùnyínrùn ti gbẹ̀mí ènìyàn méjìlá ní ìlú Katsina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

ọ̀pọ̀ awọn tó ṣaláìsí ń kígbe orí fífọ́, àti àìsàn ibà kí wọn tó kú

Ààrùn onígbá méjì (cholera) àti yírùnyírùn (meningitis) ló tún ti súyọ ní ìlú Dan Iyau, Karaje , Dutsinma nípìnlẹ̀ Katsina tó sì ti gba ẹ̀mí ènìyàn méjìlá,

olórí ìlú Dan Iyau, Suleiman Abdullahi tó jẹ́ẹ̀rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ òhún sọ pé ènìyàn mẹ́wàá ló ti kú láàárín ọ̀sẹ̀ kan

ile ẹ̀kọ́ olùkọ́ni àgbà Isa Kaita ti ìlú Dutsinma ti di títìpa lọ́jọ́ Jímọ̀ tó kọjá

lẹ́yìn tí ọmọ ilé ìwé méjé gbẹ́mì mì, sùgbọ́n agbẹnusọ ile ẹ̀kọ́ náà Malam Muntari Bala sàlàyé pé wọn ò ti ile ẹ̀kọ́ pa bíkòṣe pé àwọn lọ fún ìsinmi ráńpẹ́ ni.