Ikọlu wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjìríà àti Shiite

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọlu wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjìríà àti Shiite

Fọ́fọ́ ni gbogbo àwọn ìlooro kọ̀ọ̀kan kún fún òkúta àti agolo gáàsì ní ìlú Abuja lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà àtàwọn afẹ̀hónú hàn tó n bèèrè fún ìtúsílẹ̀ adarí ẹgbẹ́ Shiite, Sheikh Ibrahim Zakzaky.

Se ni àwọn ọmọ àwùjọ mùsùlùmí yìí ńju òkúta bá àwọn ọlọ́pàá tí àwọn òsìsẹ́ aláàbò sì fín gáàsì padà tí wọ́n fi mú púpọ̀ lára àwọn afẹ̀hónú náà.

Wọ́n ní ìbọn tí àwọn ọlọ́pàá yìn bá lára àwọn afẹ̀hónú ọ̀hún. Kò y'é ni ìhà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwà ipá náà bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọlọ́pàá kò tíì fèsì.

ICC pari iwadi lori pipa Shiites, IPOB

Àwọn ọmọ àwùjọ Shia ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà máa ń sábà bọ́ sí gbangba ígboro láti bèèrè pé kí wọ́n tú Sheikh Zakzaky, olórí ẹgbẹ́ mùsùlùmí lórílẹ́èdè Nàìjíríà sílẹ̀.

Wọ́n ní kò bá òfin mu bí wọ́n se tì í m'ọ́lẹ́ láti ọdún 2015.

  • Ẹgbẹ́ Shiite lẹgbẹ́ tó kéré jù ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà sùgbọ́n se ní wọ́n ń pọ̀ síi
  • Ẹgbẹ́ mùsùlùmí lórílẹ́èdè Nàìjíríà (IMN) tí wọ́n dá sílẹ̀ lọ́dún 1980s ni ẹgbẹ́ Shiite gangan tí Sheikh Zakzaky ń darí
  • Wọ́n dá ní àwọn ilé ìwé àti ilé ìwòsàn ti wọn ní àwọn apá àríwá kọ̀ọ̀kan
  • Wọ́n ní ìtàn ìkọlù pẹ̀lú àwọn òsìsẹ́ aláàbò
  • Ẹgbẹ́ mùsùlùmí lórílẹ́èdè Nàìjíríà ní àtìlẹyìn ilú àwọn Shia, Iran ni bi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ naa tì máa ń lọ kàwé níbẹ̀

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: