Koko iroyin: ọmọogun Nàìjìríà àti Shiite, ijinigbe Kano

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

Ikọlu wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjìríà àti Shiite

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ikọlu wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjìríà àti Shiite

Fọ́fọ́ ni gbogbo àwọn ìlooro kọ̀ọ̀kan kún fún òkúta àti agolo gáàsì ní ìlú Abuja lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà àtàwọn afẹ̀hónú hàn tó n bèèrè fún ìtúsílẹ̀ adarí ẹgbẹ́ Shiite, Sheikh Ibrahim Zakzaky.

Se ni àwọn ọmọ àwùjọ mùsùlùmí yìí ńju òkúta bá àwọn ọlọ́pàá tí àwọn òsìsẹ́ aláàbò sì fín gáàsì padà tí wọ́n fi mú púpọ̀ lára àwọn afẹ̀hónú náà.

Ìsekúpani darandaran; ọlọ́pàá mẹ́rin forí káásà ní Benue

Ọlọọpa mẹrin ti papoda lẹyin ikọlu awọn agbebọn si ibudo awọn ọlọọpa ni ipinlẹ Benue, ti eniyan mọkanla si ti di awati.

Isẹlẹ naa waye nigba ti awọn ọlọọpa n wa ọkọ kaakiri ni agbeegbe Anyibe titi to fi de ijọba ibilẹ Ayilamọ ni ipinlẹ Benue. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ rẹ ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Sàká: Oun tí orí bá yàn fún ẹ̀dá ni kó ṣe

Àkọlé fídíò,

Sàká: Oun ti orí bá yàn fún ẹ̀dá ni kó ṣe