Iléesẹ̀ Ọlọ́pàá: Ọlọ́pàá 22 farapa nínú ìkọlù Shiite

Aworan ọmọ ẹgbẹ́ Shiite ti'n fẹ̀hónú han. Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O ti to ọjọ mejidinlogorun ti awọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite ti'n fẹ̀hónú hàn fún ìtúsílẹ̀ olori wọn Sheikh Ibrahim Zakzaky.

Ile iṣẹ ọlọ́pàá nílu Abuja ni awọn tí mú ọmọ ẹgbẹ́ Shi'ite márùndínlọ́gọ́fà to kópa nínú iwode tó wáyé nílu Abuja lọjo ajé.

Ninu atẹjade kàn ti Anjuguri Manzah fi ṣòwò sí àwọn akọ̀ròyìn, o ní àwọn afurasi naa yóò fojú bá ile ejo ní kété ti àwọn ba parí ìwádìí.

Lọjọ ajé ni ikọlu wáyé láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shi'ite àti ọlọ́paa, ti ọpọ èèyàn sí farapa nínú ìṣẹlẹ náà.

Ifẹhonu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shi'ite náà kò sẹyìn bi ìjọba orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣe kọ láti tù olórí wọn, Ibrahim Zakzaky silẹ t'ohun ti bi ile ẹjọ tí pàṣẹ pé kí wọn tú silẹ.

Lọ̀dun 2015 ní wọn mú Zakzaky nínú ikọlu kan ti ọ̀ọ́dúnrún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ ti pàdánù ẹ́mi wọn.