Kókó ìròyǹ: Ìpàdé Falae àti Ọbasanjọ lórí Buhari, Ìyansẹ́lódì elétò ìlera
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Ọbásanjọ́: Àwọn ọ̀dọ́ kò gbọdọ̀ dìbò fún Bùhárí
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ́básanjọ́ tí ké pe Ààrẹ Bùhárí kó jọ̀wọ́ ìpinnu rẹ̀ láti gbe àpótí fún sáà kejì
Ààrẹ Nàìjíría nígbà kan rí, Olúṣẹgun Ọbásanjọ́ àti akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tẹ́lẹ̀, Olóyè Olú Fálaè, ṣe'pàdé bòǹkẹ́lẹ́ lórí ọ̀rò Ààrẹ̀ Muhammadu Buhari ní ọjọ́ Iṣẹ́gun.
Ìpàdé náà wáyé lẹ́hìn ọdún mọ̀kàndínlógún tí Obasanjo àti Falae ti ṣe àtakò ara wọn lórí ìbò ààrẹ l'ọ́dún 1999.
Johesu: Gbogbo òsìsẹ́ ìlera ni yóò wosẹ́ níran
Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera lorilede Naijiria, labẹ àsìá ẹgbẹ apapo awọn oṣiṣẹ ilera Johesu yoo bẹrẹ iyansẹlodi ní aago méjìlá òru ọjọ́ ìsẹ́gun.
Awọn oṣiṣẹ náà, paapa julo, àwọn tó n ṣiṣe ni awọn ile ìwòsan ìjọba àpapọ, ni yóò kọ̀kọ̀ bẹrẹ iyansẹlodi náà. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Dòdò Ìkirè jẹ́ ohun ìpanu pàtàkì nílẹ̀ Yorùba. Ìlú Ìkirè sì ni wọ́n ti máa ń se Dòdò Ìkirè
Dòdò Ìkirè: Ó dúdú lára sùgbọ́n oyin ni lẹ́nu