Wàhálà ilé aṣòfin àgbà: Ọ̀pá àṣẹ jíjígbé kìí ṣe tuntun

aarẹ̀ asofin agba Bukọla saraki duro pẹlu awọn oṣiṣẹ ile aṣofin agba niwaju ọpa aṣẹ ile Image copyright NGR Senate
Àkọlé àwòrán Ọ̀pá àṣẹ jíjígbé kiìí ṣe tuntun ní Naijria

Wahala bẹ́ sílẹ̀ ní ilé igbìmọ̀ aṣòfin àgbà orílẹ̀èdè Nàìjíríà nígbà tí àwọn jàǹdùkú kan wọ ilé tí wọ́n sì gbé ọ̀pá àṣẹ ilé lọ.

Àmọ́ṣá, ṣaaju asiko yii, ni irufẹ iṣẹlẹ tii n waye.

Diẹ ninu awọn ti a ko jọ pọ fun yin niyi.

Àwọn aṣòfin ipinlẹ Nasarawa, oṣù kéje ọdún 2014

Image copyright NGR Senate
Àkọlé àwòrán Awọn aṣofin ipinlẹ Nasarawa fi ija pẹẹta lori yiyan awọn alakoso ijọba ibilẹ nipinlẹ naa

Awọn aṣofin ipinlẹ Nasarawa fi ija pẹẹta lori yiyan awọn alakoso ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.

Ninu fọnran fidio ti o gbajugbaja lasiko naa lori ẹrọ ayelujara, gbogbo ohun ti awọn aṣofin ipinlẹ Nasarawa nigba naa lee tawọ le ni wọn fi ja, titi kan ọpa aṣẹ ile.

Awọn aṣofin ipinlẹ Rivers, oṣu keje ọdun 2013

Ni ọjọ kẹsan oṣu keje ọdun 2013, awọn a'sofin ipinlẹ Rivers fi ija pẹẹta ti wọn si lo ọpa aṣẹ ile aṣofin naa fi lu ara wọn.

Awọn aṣofin to fẹ yọ olori ile naa nigba naa, Otelemaba Amachree atawọn to gbe sii lẹyin ni wọn gbe pẹrẹgi kana nigba naa eleyi to di iṣu ata yan an yan an.

Eyi waye lasiko ede aiyede to waye laarin gomina ipinlẹ Rivers nigba naa, Rotimi Amaechi pẹlu ààrẹ nigba naa, Goodluck Jonathan.

Ile aṣoju-ṣofin, Ọjọ kọkanlelogun,Oṣu Kẹfa ọdun 2015

Image copyright Tvc news
Àkọlé àwòrán Wahala kan bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nile aṣofinṣoju lori yiyan ẹni ti yoo jẹ olori ile aṣofinsoju

Wahala kan bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nile aṣojuṣofin lori yiyan ẹni ti yoo jẹ olori ile aṣojuṣofin lọdun 2015.

Bi awọn kan ṣe n gbaruku ti Yakubu Dogara, lawọn miran wa lẹyin Gbajabiamila.

Ija to bẹ silẹ laarin igun mejeeji yii lo fa ija nla ninu gbagede ile, eleyi ti awọn kan ti gbiyanju ati gbe ọpa aṣẹ ile naa.

Ile aṣofin ipinlẹ Kano oṣu keje ọdun 2006

Image copyright NGR senate
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ kẹsan oṣu keje ọdun 2013, awọn a'sofin ipinlẹ Rivers fi ija pẹẹta ti wọn si lo ọpa aṣẹ ile aṣofin naa fi lu ara wọn

Awọn aṣofin kan gbiyanju lati yọ olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ni ile, Alhaji Tambaya Dawanu ni ọjọ kẹrinlelogun, Oṣu Keje ọdun 2006.

Ikuuku ati ẹkẹ mimu loriṣiriṣi lo farahan lọjọ naa, ti wọn si tun kan ọpa aṣẹ ile si mẹta. Ki o to di wi pe wọn gbe ọpa aṣẹ onirin miran wa sinu ijoko ile lọjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: