Johesu: Ìjọba ń fọmọ kan kẹ́ ọ̀kan lẹ́ka ìlera

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulrafiu Adeniji sọrọ lori isorogun Dokita ati osìsẹ́ ilera

Aarẹ ati Oludari ajọ to'n risi awọn agbẹbi ati olutoju alaisan ni Nàìjíríà, Abdulrafiu Adeniji ti dẹbi aawo to'n fa idasesile lopo igba ru awon eleto ilera lorileede Nàìjíríà.

O ni aisododo awọn eleto ilera ti ọpọ ninu wọn je Dokita lo faa, ti atotonu lati yanju aawo to ba waye kii so eso rere .

Adeniji se alaye pe, oti pẹ ti aisedede ti wa laarin awọn osise to ku ati awọn dokita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Iyanselodi wa ki se fun afikun owo nikan bi kii se ki atunto le ba ẹka ilera. A fẹ ki wọn se atunyẹwo ilana ti o'n ri si eto ilera lorileede Nàìjíríà ''

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn Dokita ati awọn osise ilera miran ko gba dede iye owo kannáà.

Iyanselodi lẹka ìlera làgbáyé kii se ohun àjòjì sugbọn awọn amòye ni ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà peleke.

Lọ̀jọ̀ kejindinlogun oṣù kẹrin ọdún yi ni iyanselodi mii tun bẹrẹ ni awọn ile ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ káàkiri orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Johesu to je apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ eleto ìlera ni wọn kéde iyanselodi náà eleyi ti ọpọ èèyàn tí n fesi sí.

Image copyright STEFAN HEUNIS/AFP/GETTY IMAGES
Àkọlé àwòrán Awọn alaisan lo maa n fara gba iyansẹlodi lọpọ igba lorileede Naijiria

Lara awọn to sọrọ lórí iyanselodi náà ni ẹgbẹ àwọn Dókítà orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Aare ẹgbẹ naa, Dokita Mike Ogrima, ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile isẹ BBC Yoruba ni, iyansẹlodi naa ko tọ nitori pe ẹgbẹ ti ko ba ofin mu ni Johesu.

Ogrima ni, ti ijọba ba tẹti si ohun ti Johesu n beere, o seese ko da ede aiyede sile leka ilera orileede yii.

O ni awọn ara ilu ni yoo faragba iyanselodi yii nitori kii se fun anfaani wọn, bi ko se fun awọn osise ilera nikan.

Kinni Minista ilera s si ọrọ yii?

Fun ọpọ igba la gbiyanju lati ba Minista feto ilera lorileede Naijiria sọrọ sugbọn ko gbe ipe wa.

Ona abayo kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ Johesu ati ẹgbẹ àwọn Dókítà orílẹ̀èdè Nàìjíríà daba, ni ki ijọba se atunto to peye lẹka ilera.