Ìsẹ̀lẹ̀ Cameroon: Igí wó pa akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta ọmọ Nàìjíríà

Atoka kan ni enu ona Waza natural Park, ni ekun ariwa Cameroon. Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ ilé ìwé àádọ́ta àti olùkọ́ mẹ́fà ni o lọ sí ìrìn àjò ẹ̀kọ́ náà.

Igi ti wó pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta kan, tí wọ́n kúro ní Nàìjíríà láti lọ wo àwọn ẹranko oríṣiríṣi ní ẹkùn àríwá orílẹ̀èdè Cameroon.

Alàkóso agbègbè náà, Jean Abate Edi'i, sọ wípé igi náà wo lu awon àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́hin ìji líle tí ó jà.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínlógún tó ṣèṣe nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọn gbé lọ sí Garoua, tí ó jẹ́ orí ìlú ẹkùn àríwá Cameroon.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ilé iṣé ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ agbegbe náà so wípe ọmọ ilé ìwé àádọ́ta àti olùkọ́ mẹ́fà ni o lọ sí ìrìn àjò ẹ̀kọ́ náà.

A gbọ́ wípé àwọn eerin pọ̀ ní agbègbè náà.