Lórílẹ̀èdè Zimbabwe, Ẹgbẹ̀rún mẹ́wá nọ́ọ̀sì pàdánù iṣẹ́

Àwọn noòsì jòkó sí gbàgede Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn noòsì Zimbabwe kọ̀ láti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì, lẹ́yì tí ìjọba fi mílíọ̀nú mẹ́tàdínlógún

Orílẹ̀èdè Zimbabwe tí fáwọn òṣìṣẹ́ olùtójú aláìsàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wá ní ìwé kónílé-ó-gbélé nítorí ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé láti béèrè fún àfikún owó oṣù wọn.

Nínú àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ igbá-kejì Ààrẹ Constantino Chiwenga lórí ìdí tí wọ́n fi yọ àwọn nọ́ọ̀sì náà níṣẹ́ f'ẹ̀sùn kàn wọ́n pé ìgbésẹ̀ ìyanṣẹ́lódì wọn lọ́wọ́ òṣèlú nínú.

Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ni wọ́n dá padà sílé nínú ọ̀sẹ̀ yìí l'áwọn ilé ìwòsàn ńláńlá tó jẹ́ ti ìjọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ti pé ọ̀sẹ̀ kan báyìí t'áwọn dókítà orílẹ̀èdè náà ti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì.

Ìjọba ṣàlàyé pé ìlera ará ìlú lo ṣe pàtàkì sí oùn; nítorínáà gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó yanṣẹ́lódì ni yóò gba lẹ́tà ìdádúró láti gba àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì lẹ́nu ìṣẹ́ ìtọ́jú aláìsàn.

Chiwenga jẹ́ ọ̀gá ológun tó darí ìdìtẹ̀ gbà'jọba lọ́wọ́ Robert Mugabe ní oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá.