Lẹ́yìn tó gbé ọ̀pá àsẹ ilé sálọ, ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ Omo-Agege

Aworan Ovie Omo-Agege Image copyright Ovie Omo-Agege/Twitter
Àkọlé àwòrán Ile igbimọ asofin kọwe lọ gbe ile rẹ fun Osu mẹta fun Omo-Agege

Ajọ ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu Sẹnatọ Ovie Omo-Agege lẹyin ijoko ile igbimọ asofin.

Ni ọsẹ to kọja ni ile igbimọ aṣofin kọwe lọ-gbe-ile-rẹ fun oṣu mẹta fun Sẹ́netọ̀ Omo-Agege, ṣugbọn o kopa ninu ipade awọn asofin ni Ọjọ Isẹgun ọsẹ yii.

Ileegbimọ aṣofin ti fi ẹsun kan an wipe ohun lo dari awọn janduku to yabo ile igbimọ asofin to si gbe ọpa asẹ ile lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ijoko ile ni iroyin sọ wi pe ni awọn ọlọpaa fi panpẹ ọba mu Sẹnetọ Omo-Agege ti wọn si mu lọ sinu ọkọ to wa ni ita ile igbimọ asofin naa.